Champions League: Chelsea yoo waako pẹlu Barcelona

Messi ati Suares ninu igbaradi pelu Barcelona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Apapọ Messi ati Suares jẹ iṣoro fun awọn agbabọọlu ti wọn ba koju lori papa

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Barcelona yoo gbe'na wo'ju ara wọn nigbati idije Uefa champions league ba pada sori afẹfẹ lalẹ ọjọ isẹgun.

Ọkan ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti ko lẹgbẹ yoo waye nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea yoo maa gba'lejo ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lẹyin ọdun kẹfa ti iru rẹ waye kẹyin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eyi joo jẹ idije alakọkọ fun Olivier Giroud fun Chelsea ninu idije Champions League

Awọn ẹgbẹ mejeeji ti pade ni igba mejila - lati ọdun 2000. Ipade yii ni ẹlẹẹkẹta iru rẹ fun ipele kẹrindinlogun ninu idije Champions League laarin Chelsea ati Barcelona

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti ni ilọsiwaju ninu idije yii kọja ipele akọkọ komẹsẹ o yọ fun saa marun to kọja, ti wọn si f'idirẹmi lẹẹmeji ni ipele yii.

Ipele idije Champions league yi tun jẹ ọkan ninu awọn meji ninu eyi ti FC Porto ati Liverpool FC yoo pade ara wọn.

Awọn ifẹsẹwọnsẹ Champions League ti yoo waye niyii:

Ọjọ iṣẹgun, ogunjọ osu keji

Chelsea vs Barcelona

Bayern Munich vs Besikta

Ọjọru, ọjọkọkanlelogun osu keji

Sevilla vs Manchester United

Shakhtar Donetsk vs Roma.