Olukọni ikọ Harambee stars kọ'we fi'po silẹ

idije tani yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ Afirika lọdun 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipo kẹta ni orilẹede Kenya wa ni ipin F

Olukọ ere bọọlu fun ikọ agbabọọlu orilẹede Kenya, Harambee stars, Paul Put ti kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Ninu iwe to kọ ransẹ si ajọ elere bọọlu lorilẹede Kenya, Ọgbẹni Put ni awọn nkan to n ba oun finra labẹnu lo sokunfa igbesẹ ti oun gbe naa.

Ninu atẹjade kan ti ajẹ ere bọọlu orilẹede Kenya fi sita, o ni ikọwefipo silẹ ọgbẹni Put yoo ṣe ọpọ idiwọ fun ikọ agbabọọlu orilẹede naa ninu idije tani yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ Afirika lọdun 2019, eyi ti o n lọ lọwọ.

Ajọ naa ni awọn ti bẹẹrẹ igbesẹ lati yan olukọni ere bọọlu miran, atipe titi di igba ti eleyi yoo fi bọ sii, Stanley Okumbi ni yoo maa de'le gẹgẹbi olukọni ere bọọlu fun ikọ agbabọọlu orilẹede naa.

Orilẹede Kenya wa ni ipin F idije tani yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ Afirika lọdun 2019 pẹlu awọn orilẹede bii Ghana, Sierra Leone ati Ethiopia.