Victor Moses, Oshoala gba ami ẹyẹ NFF

Awọn agbabọọlu super eagles

Oríṣun àwòrán, @nff

Àkọlé àwòrán,

NFF fun awọn agbabọọlu ni ami ẹyẹ

Awọn agbabọọlu orilẹede Naijiria meji, Victor Moses ati Asisat Oshoala ti gba amiẹyẹ kare nibi eto ami ẹyẹ Aiteo NFF fun awọn agbabọọlu lọkunrin ati lobinrin lorilẹede Naijria ti wọn pegede fi gbọọrọ jẹka.

Nibi ayẹyẹ ami ẹyẹ yii to waye lọjọ aje ni wọn ti fun agbabọọlu ọmọ orilẹede Naijiria ni, Victor Moses ni ami ẹyẹ gẹgẹbii odu agbabọọlu ọkunrin lorilẹede Naijiria ti Asisat Oshoala si gba ami ẹyẹ odu agbabọọlu lobinrin lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @thenff

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nilẹẹ Gẹẹsi ni Victor Moses ti n gba bọọlu jẹun

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nilẹẹ Gẹẹsi ni Victor Moses ti n gba bọọlu jẹun ti Asisat Oshoala si wa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Dalian Quanjian lorilẹede China.

Saaju ami ẹyẹ yii, Asisat Oshoala ti gba ami ẹyẹ odu agbabọọlu laarin awọn agbabọọlu obinrin ni ilẹ Afirika fun ọdun 2017 losu kini ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, @thenff

Àkọlé àwòrán,

Asisat Oshoala wa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Dalian Quanjian lorilẹede China.

Yatọ si ami ẹyẹ fun odu agbabọọlu lọkunrin ati lobinrin, bakanna ni wọn tun se eto amiẹyẹ fun awọn eekan agbabọọlu lorilẹede Naijiria ti wọn ti fẹyin eleyi ti wọn pe ni 'Legends XI'

Awọn agbabọọlfẹyinti ti anfani amiẹyẹ yii bọ si lọwọ ni, Anne Chiejine to jẹ asọle fu ikọ agbabọọlu obinrin orilẹede Naijiria, Super falcons nigbakanri, Augustin Eguavoen, Chirstian Chukwu, Uche Okechukwu, Felix Owolabi, Austin Okocha, Kanu Nwankwo to jẹ balogun fun ikọ agbabọọlu akọkọ ni ilẹ Afirika ti yoo gba ami ẹyẹ goolu ni idije bọọlu olympics pẹlu Dream team lọdun 1996 lorilẹede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, @thenff

Àkọlé àwòrán,

Awọn agbabọọlu fẹyinti mọkanla gba amiẹyẹ pẹlu

Bakanaa ni wọn tun fi ami ẹyẹ yii da Sẹgun Ọdẹgbami, Amiesimaka, Usiyen ati Mercy Akide-Udoh lọla.

Ko tan sibẹ, amiẹyẹ olukọni ere bọọlu to pegede ju lọkunrin bọ si ọwọ Kennedy Boboye ti ẹgbẹ agbabọọlu Plateau United nigbati Ann Chiejinne gba ami ẹyẹ fun olukọni agbaọọlu to pegede ju lobirin.

Oríṣun àwòrán, @thenff

Àkọlé àwòrán,

NFF fun awọn agbabọọlu ni ami ẹyẹ

Awọn ami ẹyẹ miran ti wọn tun fi sita nibi eayẹyẹ ami ẹyẹ Aiteo NFF to waye naa ni ami ẹyẹ fun ọjẹwẹwẹ agbabọọlu to gbamuse julọ fun ọdun2018.

Ikoumen Udoh lo gba ti ọkunrin ni abala yii ti Rasheedat Ajibade si gba ti obinrin.