Ilaji ọlọpa Naijiria lo n se dongari fun oloselu

Ọlọpa kan wa lẹyin eeyan kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ariwo ko si ọlọpa to to ni awọn eeyan orilẹede Naijiria npa

Aadọjọ ẹgbẹrun ọlọpa lorilẹede Naijiria lo n se isẹ dongari fawọn oloṣelu lorilẹede Naijiria.

Lọjọ iṣẹgun ni ọrọ yii jẹyọ nileegbimọ asofin orilẹede Naijiria lasiko ti awọn asofin agba fi n jiroro lori ikọlu ipaniyan to waye ni ipinlẹ Zamfara to wa ẹlkun iwọoorun ariwa orilẹede Naijiria.

Ni igba to n sọrọ lori ijiroro naa, Sẹnatọ to n soju ẹkun aringbungbun Bauchi lo sọ ọrọ naa nigba to n dasi ijiroro lori isẹlẹ ikọlu naa.

Sẹnatọ Mishau ni gẹgẹbi ọrọ ti alaga ajọ isakoso ileesẹ ọlọpa lorilẹede Naijiria sọ, ẹgbẹrun lọna ọtalelọọdunrun o din mẹwa (350,000) ni gbogbo ọlọpa to wa lorilẹede Naijiria. Ninu eyi ẹgbẹrunlọna igba (200,000) nikan ni ọlọpa to n sisẹ fun araalu ti ẹgbẹrun lọna aadọjọ (150,000) yooku n sisẹ aduro gboin lẹyin oloselu tabi awọn eniyan ti wọn nifọn leekannaa lawujọ eleyi ti kii se isẹ sin araalu.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Asofin Mishau ni o to ilaji gbogbo ọlọpa orilẹede Naijiria ti wọn ko si nidi isẹ igbofinro mọ

Laipẹ yii ni awọn janduku agbebọn kan kọlu agbegbe ijọba ibilẹ Zurmi ni ipinlẹ Zamfara leyi ti awọn eeyan kaakiri orilẹede Naijria ati lagbaye ti bu ẹnu atẹ lu.

Lẹyin ọpọ ijiroro lori ọrọ ọhun ni ile wa fi ẹnu ko wipe ki ijọba apapọ o pasẹ fun ileesẹ ọmọogun ofurufu lati lo anfani fifo loju ofurufu lati fi se awari ibuba awọn agbebọn to kun igbo nla kaakiri ki wọn si le wọn jade.

Bakanna ni ile tun ke si ijọba apapọ orilẹede Naijiria lati tubọ ba orilẹede Niger ati Chad sọrọ lọna ati di gbogbo aaye ti awọn janduku agbebọn naa n sa pamọ si.

Lara awọn ifẹnuko miran ti ile asofin agba orilẹede Naijiria gbe jade lori ọrọ ikọlu ipinlẹ Zamfara naa ni idasilẹ ibudo awọn atipo, IDP ni ipinlẹ Zamfara lati lee fun awọn eeyan ipinlẹ naa ti wọn ti di alarinkiri ati alainilelori ni aaye lati fi ori pamọ si.