Champions League: Messi ra igba pada fun Barcelona lojude Chelsea

bọọlu wọ awọn Chelsea Image copyright Press Association
Àkọlé àwòrán Goolu Messi ni ikejidinlogun ti yoo gba wọle fun Barcelona

Goolu akọkọ ti gbajugbaja agbabọọlu ikọ Barcelona ni, Lionel Messi yoo gba wọle ikọ Chelsea ni ifẹsẹwọnsẹ mẹsan ti o ti koju ikọ naa lo fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ni anfani ọmi ni abala akọkọ ipele komọsọ o yọọ akọkọ nibi idije Champions league to waye ni alẹ ọjọ isẹgun.

Nibi ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni papa isire Stamford Bridge, awọn agbabọọlu chelsea ko jẹ ki odu agbabọọlu lọ o ri imu mi, ti agbabọlu Chelsea, Willian si gba bọọlu ba irin ojuule lẹẹmeji ọtọọtọ ki o to gba ẹlẹkẹẹta wọ inu awọn ikọ Barcelona ni isẹju kejilelọgọta ifẹsẹwọnsẹ naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Chelsea mọ wipe ikọ Barcelona kii se ẹran rirọ rara

Eku ikọ agbabọọlu Barcelona ko lee ke bi eku ni Stamford Bridge fun ọpọlọpọ akoko ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi waye sugbọn se wọn ni aṣiṣe o kan ọgbọn, aṣiṣe ti agbabọọlu Chelsea, Andreas Christensen ṣe to fi gba bọọlu si ọwọ Andres Iniesta to jẹ agbabọọlu Barcelona lo fun Messi lanfani lati yẹ awọn Chelsea wo nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ku isẹju mẹẹdogun ko pari.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Goolu ti Willian gba wọle ni ikọkanla rẹ fun Chelsea ni saa yii

Ninu ifẹsẹwọnsẹ miran to tun waye ninu idije Champions league ni alẹ ọjọ isẹgun, ikọ agbabọọlu Bayern Munich to pankẹrẹ si idi Bekistas pẹlu ami ayo marun si odo.

Ni isẹju kẹrindinlogun ni adari ifẹsẹwọnsẹ naa ti yọ kaadi pupa jade fun ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Bekistas, Domagoj Vida ti iye awọn agbabọọlu ikọ naa si di mẹwa.

Agbekalẹ Conte lati koju Barca

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Asise nla lo ti igi bọ oju ilana ati afojusun Conte olukọni Chelsea

Olukoni ere bọọlu fun ikọ Chelsea, Antonio Conte pẹlu ikọ rẹ mọ wipe ikọ Barcelona kii se ẹran rirọ rara ati wipe wọn nilo ikoraẹni ni ijanu to muna doko pẹlu ipinnu latikogoja ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ikọ naa.

Diẹ lo ku ki eyi bọ sii fun wọn bi kii ba se ti asise to waye ni isẹju karundinlọgọrin ifẹsẹwọnsẹ naa, ti o si seese ko jẹ odiwọn nla-nla ti yoo sọ ẹni ti yoo kogoja laarin ikọ mejeeji yii lasiko ti wọn ba tun n waako ni abala keji ipele yii ti wọn yoo gba ni papa isire Camp Nou lorilẹede Spain.

Agbabọọlu ikọ Chelsea, Willian tan bii oorun ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu bi abiku rẹ se sọ oloogun ikọ Barcelona di eke pẹlu awọn ere bọọlu ari-kọ-haa-hiin.

Messi gba bọọlu wọ inu awọn Chelsea fun igba akọkọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iniesta lo ṣiṣẹ goolu fun Messi lẹyin ti aṣiṣe ti waye lati ọdọ Andreas Christensen ti ikọ Chelsea

Bi o ti lẹ jẹ wi pe ọpọ awọn ikọ agbabọọlu yala ti orilẹede ni tabi ti ẹgbẹ agbabọọlu kaakiri agbaye ni odu agbabọọlu jẹun ni, Lionel Messi ti gba bọọlu wọ sugbọn ko ri bẹẹ fun pẹlu ikọ agbabọọlu Chelsea.

Ẹdẹgbẹrin o le ọgbọn isẹju lo ti fi koju ikọ Chelsea to jẹ wipe otubantẹ naa ni ki o to di wipe anfani si silẹ fun ni isẹju karundinlọgọrin ifẹsẹwọnsẹ yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eku ikọ agbabọọlu Barcelona ko lee ke bi eku ni Stamford Bridge fun ọpọlọpọ akoko ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi waye

Iniesta lo ṣiṣẹ goolu yii lẹyin ti aṣiṣe ti waye lati ọdọ Andreas Christensen ti ikọ Chelsea.

Messi ko besu-bẹgba ni kete ti bọọlu tẹẹ lẹsẹ lati ọwọ Iniesta lo tẹ bọọlu si ibi ti ọwọ aṣọle Chelsea, Courtois lati fun Barcelona ni anfani pinpin ami ayo Andreas Christensen naa.

Kini ọrọ ti awọn olukọni ikọ Chelsea ati Barcelona sọ?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn olukọni ikọ mejeeji lo mọ wipe isẹ si n bẹ ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ wọn

Olukọni ikọ Chelsea, Antonio Conte ni: " Diẹ lo ku ki a bọ si ilana bọọlu gbigba ti ko ni abawọn kankan ninu. A ṣe aṣiṣe kan ṣoṣo to ko ba bọọlu wa paapaa nigba ti o ba nkoju ikọ to ni awọn agbabọọlu bii Messi, Iniesta and Suarez.

" O ṣeni laanu pe Messi, Iniesta and Suarez yii pari pẹlu esi ti a ri gba yii.

" A gba bọọlu gidi ninu Messi, Iniesta and Suarez yii inu mi si dun nitori awọn agbabọọlu mi fi ọpọlọpọ ipinu si Messi, Iniesta and Suarez yii wọn si tẹle ilana gbogbo ti a la kalẹ.

" A gbọdọ ṣetan lati jẹ ọpọlọpọ iya papọ ti a ba pada de ọdọ Barcelona, sugbọn ṣa a gbọdọ tun mura lati si awọn anfani silẹ fun ara wa lati lee gba bọọlu wọ inu awọn tiwọn naa."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipade di osu kẹta lati mọ agba laarin ikọ Chelsea ati Barcelona

Olukọni Barcelona, Ernesto Valverde ni: " A fi ọpọlọ aaye silẹ fun Willian lati maa gba bọọlu kikankikan si oju ile wa. Bọọlu ti wọn gba fun un ko labawọn rara, ọpọlọ pipe ni oun pẹlu fi tẹ bọọlu yii lai labawọn rara.

O ṣeeṣe ki inu wọn dun si esi ifẹsẹwọnsẹ yii sugbọn ohunkohun lo lee ṣẹlẹ ni papa iṣire Camp Nou."

Related Topics