CAF Champions League: MFM ati Plateau Utd gbe'gba oroke

Plateau United ninu idije kan

Oríṣun àwòrán, @LMCNPFL

Àkọlé àwòrán,

Plateau United na Eding Sports Club pẹlu ami ayo kan

Ẹgbẹ agbabọọlu ti o pegede julọ lorilẹede Naijiria bayi, Plateau United ati MFM FC ti tayọ lati kopa ninu ipele ti o kan ninu idije CAF Chamipions league bayii.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji gba aridaju eyi lọjọru ninu ifẹsẹwọnsẹ ti o waye ninu idije naa.

Bi MFM FC se n bori ẹgbẹ agbabọọlu AS Real Mamako lorilẹede Mali ni papa iṣere Agege pẹlu ami ayo kan si odo ni Plateau United pẹlu n f'agba han Eding Sports Club ti orilẹede Cameroon ni Yaounde pẹlu ami ayo kan s'odo.

Eyi jẹ igba akọkọ ni ọdun mẹtala ti ifẹsẹwọnsẹ idije CAF yoo waye nipinlẹ Eko ati igba akọkọ fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu MFM FC.

Oríṣun àwòrán, @LMCNPFL

Àkọlé àwòrán,

MFM FC ti gbe'gba oroke lati kopa ninu ipele ti o kan ninu idije CAF

Ni bayii, ẹgbẹ agbabọọlu Plateau United yoo maa kọju Etoile Du Sahel ti Tunisia ni ipele keji ti ẹgbẹ agbabọọlu MFM FC n duro lati mọ alatako wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: