Iwobi yoo koju AC Milan ninu idije Europa

Awọn agbabọọlu Arsenal nduro lati ya fọto Image copyright European Photopress Agency
Àkọlé àwòrán Ikọ Arsenal nlepa ife ẹyẹ Europa lati lee pada si idije Champions league ni saa to n bọ

Ikọ agbabọọlu Arsenal yoo maa koju ẹgbẹ agbabọọlu AC Milan lati orilẹede Italy nibi ipele ko mẹsẹ-o-yọ ọ ti idije Europa.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ikọ Arsenal fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ abala keji ipele to saaju idije yii,

nigbati ikọ Ostersund lati orilẹede Sweden kede pe aile ja lojude baba mi ko dehin fun un,

to si na Arsenal pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan ni papa isere Emirate sugbọn Arsenal ni ore ọfẹ lati tẹsiwaju nitoripe awọn pẹlu ti lu Ostersund mọle pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọ kan.

Nibayii, ikọ AC Milan ni Alex Iwobi, agbabọọlu lati orilẹede Naijiria ati awọn akẹẹgbẹ rẹ yoo maa ba waa ko ninu ifẹsẹwọnsẹ ti ọpọ onwoye ere bọọlu ti sapejuwe gẹgẹbii eyi ti yoo gbomimu gidigidi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Odu ni ikọ agbabọọlu AC Milan lawujọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu nilẹ Yuroopu

Ẹkọ ko soju mimu fun Arsenal lọwọlọwọ bayi

Ko si ẹni to lee kọ iyan ikọ agbabọọlu AC Milan kere lawujọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti iyọ dun ọbẹ wọn nilẹ Yuroopu

pẹlu bo ti se gba ife ẹyẹ Champions league ni ẹẹmeje ọtọọtọ, bi o tilẹ jẹ wipe nkan o dan mọran fun ẹgbẹ agbabọọlu naa lẹnu ọjọ mẹta yii.

Bakanna ni ikọ Arsenal pẹlu ko see fi ọwọ rọ sẹyin lagbo idije ere bọọlu nilẹ Yuroopu sugbọn ẹkọ ko soju mimu fun un lẹnu lọwọlọwọ yii

nitori baa se n sọrọ yii, ipo kẹfa ni Arsenal wa ni atẹ idije liigi ilẹ Gẹẹsi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn onwoye n sọ wipe ifẹsẹwọnsẹ naa yoo gbomimu fun Alex Iwobi atawọn akẹgbẹ rẹ

Ẹkunrẹrẹ bi wọn se pin ifẹsẹwọnsẹ yooku:

  1. Lazio yoo koju Dynamo KievRB Leipzig yoo koju Zenit St Petersburg
  2. Atletico Madrid yoo koju Lokomotiv MoscowCSKA Moscow yoo koju Lyon
  3. Marseille yoo koju Athletic BilbaoSporting CP yoo koju Viktoria Plzen
  4. Borussia Dortmund yoo koju FC SalzburgAC Milan yoo koju Arsenal

Related Topics