AWCON: Ṣé Falcons yọò tẹ̀síwájú tàbí tẹ̀lé Ghana jáde ní ìdíje AWCON?

Ikọ Falcons

Oríṣun àwòrán, @CAF_Online

Àkọlé àwòrán,

Ifẹsẹwọnsẹ Super falcons ati Equitoria guinea yoo fun awọn agbabọọlu orilẹede Naijiria naa ni anfani ati gba ẹsan bi ikọ Equitorial guninea kan naa ṣe yọ ọwọ wọn lawo ati kopa ni idije olympics

Ikọ agbabọọlu obinrin orinlẹede Naijiria, Super Falcons yoo maa waako pẹlu awọn akẹgbẹ wọn lati orilẹede Equitorial guninea lọjọ abamẹta lati mọ boya ọna itẹsiwaju lọ si ipele to kangun si aṣekagba ni yoo ṣi silẹ fun wọn tabi ọna ile.

Idije ife ẹyẹ fun awọn agbabọọlu obinrin ti o nlọ lọwọ lorilẹede Ghana ko tii fi gbogbo ara ṣe ẹnuure fun ikọ falcons lẹyin ti wọn fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kan, ti wọn si tun bori ayo kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ami ayo kan si odo ni ikọ Bayanabayana fi gbo ewuro si oju super falcons ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ ki wọn to pada wa bori ikọ Zambia pẹlu ayo mẹrin.

Oríṣun àwòrán, @CAF_AWCON

Àkọlé àwòrán,

Ghana kuna lati tẹsiwaju ninu idije AWCON ti o n gbalejo

Lẹyin ti ikọ Ghana, ọkan lara awọn ikọ agbabọọlu obinrin ti o n moke julọ ni ilẹ Afirika ti dagbere fun idije naa nigba ti wọn gba ọọmi oni goolu kọọkan pẹlu Cameroun ni ọjọ , oju gbogbo yoo wa lara ikọ Falcons boya awọn pẹlu yoo rele ni tabi wọn yoo tẹsiwaju ninu idije naa.

Ju gbogbo rẹ lọ, ifẹsẹwọnsẹ Super falcons ati Equitoria guinea yoo fun awọn agbabọọlu orilẹede Naijiria naa ni anfani ati gba ẹsan bi ikọ Equitorial guninea kan naa ṣe yọ ọwọ wọn lawo ati kopa ni idije olympics lasiko ifẹsẹwọnsẹ tani yoo kopa to waye lọdun 2015.

AWCON: Ikọ̀ Super Falcons ṣetán láti kojú Equatorial Guinea

"Ikọ Super Falcons ṣẹṣẹ n mẹyẹ bọ lapo ni ninu idije AWCON,'' Ẹlẹsẹ ayo, Francisca Ordega fun ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Naijiria lo sọ bẹẹ.

Ordega to wa lara awọn agbabọọlu to gbayo wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ Naijria ati Zambia ní àwọn ṣetán láti kojú Equatorial Guinea lẹyin ti wọn na Zambia ni alubolẹ.

Àkọlé fídíò,

Ikọ̀ Super Falcons ṣetán láti kojú Equatorial Guinea

Ẹ o ranti pe Naijiria fidirẹmi pẹlu ayo kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba ninu idije AWCON to n lọ lọwọ lorilẹede Ghana.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

#AWCON: Falcons f'agbà han Zambia pẹ̀lú àmì ayò 4-0

Ẹgbẹ agbabọọlu obinrin orilẹede Naijiria, Super Falcons fi agba han akẹgbẹ wọn lati orilẹede Zambia pẹlu ami ayo mẹrin si odo.

Oríṣun àwòrán, @NGSuper_Falcons

Àkọlé àwòrán,

Super falcons ti kọkọ fidrẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba pẹlu South Africa

Nibi idije ife ẹyẹ awọn agbabọọlu obinrin Afirika to n lọ lọwọ lorilẹede Ghana.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

'Mo máa ń fi orin ìbílẹ̀ tiwa n tiwa gbá ti òkè òkun lẹ́gbẹ̀ẹ́'

Super Falcons ti kọkọ fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ pẹlu ikọ Bayanabayana ti South Africa.

Ami ayo kan ni South Africa fi gbẹyẹ mọ Super Falcons lọwọ.

Ugochi Desire Oparanozie lo gba ayo akọkọ ati ikẹta wọle, Francisca Ordega ati Amarachi Okonkwo lo gba meji yooku wọle.

Ninu ọrọ rẹ olukọni ikọ Super falcons, Thomas Dennerby ṣalaye fawọn akọroyin lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa pe lootọ ijakulẹ waye ni ifẹsẹwọnsẹ akọkọ naa ṣugbọn o ni oun ko jẹ ki o ko irẹwẹsi ọkan ba oun tabi ikọ naa.

Oríṣun àwòrán, @NGSuper_Falcons

Àkọlé àwòrán,

Falcons lo gba ife ẹyẹ AWCON julọ

Agbabọọlu Naijiria, Francisca Ordega ni wọn mu gẹgẹ bii agbabọọlu to yaranti julọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ghana f'agbahan Falcons ninu Idije WAFU

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Idije Wafu Women's Cup ni akọkọ iru rẹ fun awọn agbabọọlu obirin lafrika

Ikọ Black Queens orilẹẹde Ghana ti fagba han akẹgbẹ wọn Super Falcons Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba idije awọn obirin ẹkun iwọ oorun Afrika (Wafu Women's Cup).

Ami ayo marun si mẹrin ni wọn fi tawọnyọ ninu gbele-o-gbaa sile eyi to mu ki wọn tẹsiwaju fun aṣekagba idije akọkọ Wafu fun awọn obirin to'n waye nilu Abidjan.

Ṣaaju ni wọn ko gba ami ayo kọọkan lasiko ti wọn la kalẹ fun ifẹsẹwọnsẹ naa.

Awọn ikọ Falcons lo kọ jẹ nigba ti Alice Ogebe gba ayo wọle fun wọn ni isẹju kẹjọ.

Faustina Ampah da ayo naa pada ki asiko ti wọn la kalẹ o to pe.

Oríṣun àwòrán, @NGSuper_Falcons

Àkọlé àwòrán,

Awọn ikọ Falcons lo kọ je nigba ti Alice Ogebe gba ayo wọle fun wọn ni isẹju kẹjo

Ni bayi Ghana yoo koju Côte d'Ivoire ninu aṣekagba lọjọ aiku nigba ti awọn Falcons ati Mali yoo jọ wọya ija fun ipo kẹta lọjọ abamẹta.

Ẹwẹ, ajọ eleto ere bọọlu fun ilẹ Afrika (CAF) ni awọn yoo ṣe amulo ẹrọ ayaworan to'n ṣe iranwọ fun adari ere bọọlu (VAR) fun igba akoko lọjọ abamẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ laarin Wydad Athletic Club tilu Morocco ati TP Mazembe ti DR Congo ninu idije Total CAF Super Cup.

Iyọnda ti wa lati ọdọ igbimo ajọ to'n mojuto ọrọ bọọlu afẹsẹgba lagbaye (IFAB) ati ajọ to'n mojuto ọrọ bọọlu (FIFA) pe ki wọn ṣe amulo ẹrọ ayaworan naa ninu ifẹsẹwọnsẹ laarin awọn ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ọrọ ri bẹẹ pẹlu bi wọn ti ṣe ni aṣeyọri ninu ayẹwo igbaradi ninu idije Total African Nations Championship to waye lọdun 2018 eleyi ti awọn onimọ FIFA ṣe amojuto rẹ.

Wọn ti ṣaaju lo ẹrọ naa ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye nilu Casablanca, Marrakech ati Tangiers.

Akọwe agba fun ajọ CAF Amr Fahmy ṣe apejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi oun manigbagbe fun ere bọọlu nilẹ afrika.

O ni yoo si lapa lori idagbasoke ere bọọlu lafrika.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: