Carabao Cup: Tani yoo ja mọ lọwọ laarin Arsenal ati Man City?

Arsene Wenger

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹnu ti nku Arsene Wenger lori aigba ife ẹyẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal yoo koju ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ni ọjọ aiku ninu aṣekagba idije ti Carabao Cup.

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti o pegede ninu idije Europa ni ọjọọbọ lẹyin ti wọn fidirẹmi pẹlu ami ayo kan si meji ṣugbọn ti wọn farale ami ayo mẹta ti wọn jẹ ninu idije akọkọ ni Sweden.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City naa ti wa ni digbi bayi, bi o tilẹ jẹ wi pe wọn ni ijakulẹ ninu idije FA ni ọjọ aje nigbati wọn fidirẹmi pẹlu ami ayo kan si odo ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Wigan Athletic.

Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United yoo maa gbalejo ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni papa iṣere Old Trafford ninu idije Premier League ni ọjọ aiku kan naa nigbati ẹgbẹ agbabọọlu Crystal Palace yoo maa gbe'na woju ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham Hotspur.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ṣe ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal le gba ife yi lọwọ Manchester City

Ṣaaju, awọn idije wọnyii yoo waye ni ọjọ abamẹta ninu idije Premier League:

  • Leicester City vs Stoke City
  • AFC Bournemouth vs Newcastle United
  • Brighton & Hove Albion vs Swansea City
  • Burnley vs Southampton
  • Liverpool vs West Ham United
  • West Bromwich Albion vs Huddersfield Town
  • Watford vs Everton.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: