Ileesẹ ọmọogun Naijiria koro oju si iwadi Amnesty International

Aarẹ Buahari atai awọn ọgaagba ologun duro ninu asọ ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ileesẹ ologun ni ko si ohun to lee mu ki orilẹede Naijiria tẹriba fun ifẹ inu Amnesty International

Ileesẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ti salaye wipe ijọba orilẹede Naijiria ati awọn ẹka isẹ ijọba gbogbo lorilẹede Naijiria ko ni tẹriba fun awọn ohun ti ajọ naa nfẹ yala nisisiyi tabi ni ọjọ iwaju.

Alaye yii n waye lẹyin-o-rẹyin abajade iwadi kan eleyii ti ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International gbe jade wipe ọpọlọpọ awọn ọdọkunrin ni awọn ọmọogun Naijiria n sọ si atimọle lai mọwọ mẹsẹ ninu iwa ẹsẹ kankan.

Ileesẹ ọmọogun lorilẹede Naijiria ni ohun ti ko tọna gbaa ni ajọ naa se si awọn agbaagba ileesẹ ologun ti wọn n fi tọsan toru laagun lori bi alaafia yoo se jọba lawọn agbegbe ti omi wahala ti n sun jade lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ileesẹ ologun ni bi ajọ Amnesty International yẹ ko tunfọnrere awọn ohun to se to dara

Lara awọn ẹsun ti ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International fi kan ileesẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ni wipe o keti ikun si ilana idaabo bo ẹtọ ọmọniyan, nipa ipaniyan ti ko ba ofin mu, kikọ oju oro si awọn oniroyin, fifi ipa mu awọn to n se iwọde alaafia ati bẹẹbẹẹ lọ.

"Gbogbo awọn ti wọn fi satimọle ni wọn ko fun laaye lati ri awọn agbẹjọro wọn. Ẹẹdẹgbẹta o din meje awọn eeyan ti wọn fi si ahamọ ni wọn tu silẹ losu kẹrin ti awọn ọtalelẹẹdẹgbẹrin miran si tun gba ominira ni osu kẹwa. Ni osu kẹrin, ẹgbaaji ati ẹẹdẹgbẹrun (4, 900) awọn eeyan lo wa ni ahamọ ologun to wa ni bareke Giwa, Maiduguri ni ibiti wọn ti fun wọn mọra gagaga bi ẹja inu yin-in-yin."

Ileesẹ ologun orilẹede Naijiria koro oju si abajade iwadi ajọ yii naa eleyi to ni o n gbiyanju ati 'kọ ẹyin araalu ati ajọ orilẹede agbaye si awọn ologun.'

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ileesẹ ọmọogun Naijiria ni ajọ Amnesty International fẹ kọ ẹyin araalu araalu si kọ ileesẹ ọmọogun

Ileesẹ ologun ninu atẹjade rẹ ni gẹgẹbi ileesẹ ti ofin ti lẹyin, ileesẹ ologun ko lee kọ oju ibọn si araalu nitori ojuse to wa fun ni lati daabo bo araalu.

O ni abajade naa lee kun ara ọgbọn alumọkọrọyi lati dina ajọsepọ to n waye lọwọlọwọ yii laarin orilẹede Naijiria ati Amẹrika lati lori gbigbogun ti iwa igbesunmọmi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ileesẹ ologun Naijiria ni iwadi Amnesty International ko bu iyi kun ilakaka awọn adari rẹ

"Ajọ Amnesty International kuna lati sọrọ lori igbẹjọ to n lọ lọwọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ati idajọ fun awọn to jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn. Gbogbo awọn ti wọn da silẹ lori wipe wọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ti a si ti da pada saarin ilu le ni ẹẹdẹgbẹta."

Ni ọjọọbọ, ọjọ kejilelogun osu keji ọdun 2018 ni ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International gbe abajade iwadi kan jade lori ọrọ ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria lọdun 2017 ninu eyi ti o ti mu ẹnu ba ẹsun pe awọn ologun lorilẹede Naijiria n tẹ oju ẹtọ awọn araalu mọlẹ paapaa lawọn ẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria nibiti wahala igbesumọmi ti n waye.