Arsenal fẹ gba ife Carabao fun Wenger

Bellerin ati awọn agbabọọlu Manchester city n waako

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ikọ agbabọọlu arsenal ni awọn setan lati gba ife ẹyẹ Carabao fun olukọni wọn, Arsene Wenger.

Alex Iwobi, ọmọ orilẹede Naijiria to n gba bọọlu jẹun ni ikọ Arsenal pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ yoku ni awọn setan lati gba ife ẹyẹ Carabao fun olukọni wọn, Arsene Wenger.

Agbabọọlu ikọ Arsenal kan, Hector Bellerin lo fi ọrọ yii to BBC leti.

Olukọni ikọ agbabọọlu Arsenal, Arsene Wenger ko gba ife ẹyẹ yii ri lati igba to ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ni ọdun mọkanlelogun sẹyin, sugbọn agabọọlu ọwọ ẹyin fun Arsenal Bellerin ni eyi gan an ni yoo se koriya fun awọn lasiko ti ikọ naa ba n waako pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city ni irọlẹ ọjọ aiku.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Alex iwobi ati awọn akẹgbẹ rẹ fẹ gba ife Carabao fun Wenger

Ikọ Manchester city ni ọpọ onwoye bọọlu fi oju si lara lati gba ife ẹyẹ yii niwọn igbati o jẹ wipe ami mẹtadinlọgbọn ni ikọ naa fi ju ikọ Arsenal lọ bayii lori atẹ igbelewọn liigi premiership ti saa 2017/2018 to n lọ lọwọ.

Bellerin sọ fun BBC Radio 5 live wipe: "A gbọdọ se eyi fun un. Gbogbo wa la mọ wipe ọga wa ko ti gbe ọwọ le ife yii ri lati bi ogun ọdun to ti wa nibi. Eyi gan tun jẹ iwuri fun wa."

Bi o tilẹ jẹ wipe aja ikọ Man city lo n le waju bayii ninu idije liigi premiership ni ilẹ Gẹẹsi, sugbọn ife ẹyẹ FA bọ mọọ lọwọ lọjọ aje to kọja nigbati ikọ wigan gbẹyẹ mọọ pẹlu ami ayo kan dondon, lati fi opin si ireti ife ẹyẹ mẹrin to ti n ni bọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

fun ogun ọdun ni Wenger ti n ba ijaku pade ni idije yii

Bellerin ni "ikọ naa lee maa gbona girigiri bayii sugbọn ko si ẹni to kọja lilu.

"Lootọ wọn ni ẹyin to duro daadaa eyi ti wọn ko ni tẹlẹ. Sugbọn ti ikọ Wigan ba lee se awa pẹlu lee se niyẹn."

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ko tii gba ife ẹyẹ yii lati nkan bii ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin lẹyin ti wọn ti na ẹgbẹ agbabọọlu Sheffield Wednesday pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan ni papa isire Wembley labẹ akoso olukọni wọn nigba naa, George Graham.