Man City gbo ewuro soju Arsenal ninu idije asekagba ife ẹyẹ Carabao

Manchester City gba ife eye Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O ti to ọdun mẹwa ti Vincent Kompany ti wa ninu ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City

Egbẹ agbabọọlu Manchester City ti gba ife ẹyẹ wọn akọkọ labẹ akọnimọọgba wọn, Pep Guardiola loni, nigba ti wọn lu ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ni papa isere Wembly ni ami ayo mẹta si odo.

Sergio Aguero ni o sọ bọọlu si Claudio Bravo ko to di pe Bravo gba sinu àwọ̀n ti goolu akọkọ fi wọle fun Man City.

Lẹyin eyi ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu ọun, Vincent Kompany yi ẹlẹẹkeji wọnu awọn pẹlu sọọti ti Ilkay Gundogan sọ sii.

David Silva gba goolu ẹlẹẹkẹta wọnu awọn, eyi ti o fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ni amin ayo Meta ti wọn fi tayọ awọn akẹgbẹ wọn ninu ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Manchester City gba ife eye

Egbẹ agbabọọlu Arsenal naa kofi bẹẹ gbẹ́ní wa, a rii ti Pierre-Emerick Aubameyang gbiyanju lati gba bọọlu soju ile, sugbọn ti gbogbo igbiyanju ọun ja si pabo.

Ife ẹyẹ yii nikan ni ife ẹyẹ abẹle ti akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal Arsene Wenger ko tii gba latigba to ti n dari ẹgbẹ agbabọọlu ọun.

Eyi jẹ igba kẹta ti yoo padanu ninu asekagba ife ẹyẹ yii, lati nnkan to le l'ogun ọdun to ti n dari ẹgbẹ agbabọọlu ọun.

Ki ni oun to kan?

Egbẹ agabọọlu Manchester City ati ẹgbẹ agbabọlu Arsenal yoo pade ni ọjọbọ to n bọ yii, ni papa isere Emirates.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ife eye miran tun bọ mọ Arsenal lọwọ

Egbẹ agbabọọlu Arsenal yoo gba awọn akẹgbẹ wọn ninu ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea l'alejo ni ọjọ isinmi to n bọ, nigba ti Arsenal ati Brighton yoo figa-gbaga saaju lọjọ isinmi ọun bakan naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: