Alaga ajọ Inec ni kaadi idibo yoo wa fawọn oludibo loṣu karun

Alaga ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n wọ tọ ipese kaadi idibo fun awọn oludibo

Alaga ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ti sọ wipe ni ọsẹ kini oṣu karun lawọn eeyan ti ko tii gba kaadi idibo wọn yoo ri gba.

Ọjọgbọn Yakubu sọrọ yii nibi ipade to n lọ lọwọ pẹlu awọn ẹgbẹ ajafẹtọ gbogbo nilu Abuja.

Ipade ọhun to n lọ lọwọlọwọ bayii jẹ ipade oloṣu mẹta-mẹta ti ajọ INEC maa n ṣe pẹlu awọn ẹgbẹ ajafẹtọ jakejado orilẹede Naijiria lati bun wọn gbọ lori bi nkan se n lọ si lori ilana ati eto idibo lorilẹede Naijiria.

Lara awọn nkan ti wọn n gbe yẹwo nibi ipade naa ni igbaradi fun eto idibo ọdun 2019, ibi ti nkan de duro lori eto iforukọsilẹ awọn oludibo to n lọ lọwọ pẹlu igbaradi fun eto idibo ni gomina ni ipinlẹ Ekiti.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọgbọn Yakubu sepade pẹlu awọn ẹgbẹ ajafẹtọ gbogbo l'Abuja

Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n wọ tọ ipese kaadi idibo fun awọn oludibo lorilẹede Naijiria.

Bi awọn oludibo kan to ti forukọsilẹ ti se n pariwo pe awọn o ri kaadi idibo wọn gba, lawọn ajọ INEC pẹlu n pariwo wi pe awọn araalu kan naa kuna lati wa gba kaadi idibo.

Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ...

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: