Samir Nasir ko ni gba bọọlu f'oṣu mẹfa

Samir Nasir lori papa pẹlu iko agbabooly Turkey Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Samir Nasir ko ni agbabọọlu kankan lọwọlọwọ bayii

Agbabọọlu fun ẹgbẹ Manchester City nigba kan ri, Samir Nasri ko nii gba bọọlu fun oṣu mẹfa nitori itọju ati abojuto ailera ti o gba ni ile-iwosan kan ni Los Angeles ni ọdun 2016..

Nasri, ti o jẹ ọmọ ọgbọn ọdun, gba itọju lakoko isinmi, ṣugbọn itọju yi lodi si awọn ilana ti ajọ to n gbogun ti oogun oloro lilo laarin awọn elere idaraya lagbaye (World Anti-Doping Agency) gbe kalẹ.

Agbẹjọro fun Nasir sọ fun BBC wipe ajọ Uefa ti pinnu lati fun Nasir ni iwe idaduro diẹ lẹnu bọọlu gbigba.

Ẹka ere idaraya BBC ranṣẹ si Uefa lati dahun awọn ibeere lori ọrọ yii sugbọn wọn ko tii fesi bayi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Manchester City ran Samir si iko Sevilla

Nasri kuro ninu ẹgbẹ Antalyaspor ti orilẹede Turkey ni oṣu kinni ọdun, ti o si gba itọju lati ile-iṣẹ iwosan aladani kan ti won pe orukọ rẹ ni, Drip Doctors ni iyara igbafẹ hotẹẹli rẹ.

Ni akoko ti a n sọrọ rẹ yii, Nasir wa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Sevilla, lasiko naa si ni aworan rẹ kan jade nibiti o duro papọ pẹlu ọkan lara awọn alakoso ile iṣẹ naa, Jamila Sozahdah.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si:

Related Topics