Ko daju wipe Neymar le kopa ninu idije Champions League

Aworan Neymar

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ agbabọọlu PSG nse adura ki ara Neymar da ki o to di ọjọ isẹgun

O ṣeeṣe ki agbabọọlu ti owo ori rẹ pọju lagbaye, Neymar, ma kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ẹgbẹ rẹ, PSG pẹlu Real Madrid ninu idije Champions League.

Eyi ko ṣẹyin bi o ti ṣe fi kokosẹ rẹ rọ ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lọjọ aiku pẹlu Marseille.

Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ n ṣe adura ki ara rẹ da ki o to di ọjọ isẹgun.

Ṣaaju nibi ifẹsẹwọnsẹ wọn ninu idije Champions League, Real Madrid fagbahan ẹgbẹ agbabọọlu PSG pẹlu ayo mẹta si ọkan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Neymar ninu idije Champions League pelu PSG

Cristiano Ronaldo ati Marcelo wa lara awọn ti wọn gba bọọlu wọle fun Real Madrid nibi ifẹsẹwọnsẹ naa.

Oku ki Neymar ṣ'ara giri lati le kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ pataki eleyi ti yoo waye lọjọ isẹgun.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: