Bolt tọwọbọwe adehun pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu kan

Usain Bolt Image copyright Gallo Images
Àkọlé àwòrán Usain Bolt ti si oju kuro nidi ere sisa si ere bọọlu afẹsegba

Gbajugbaja elere ori papa, Usain Bolt sọ pe oun ti tọwọbọwe adehun lati darapọmọ ẹgbẹ agbabọọlu kan.

Lori oju opo facebook rẹ lo ti kede ọrọ naa.

Ṣugbon o kọ lati darukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa.

O ni ki ẹnikẹni to ba fẹ ẹ mọ orukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa pade oun lọjọ iṣẹgun.

Awọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ si nii daba orukọ ẹgbẹ ti wọn lero wi pe o le jẹ

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mamelodi Sundowns figbakan gbalejo Usain Bolt

Laipe yi ni aworan Usain Bolt gba ori ẹrọ ayelujara nibi ti o ti'n ṣe igbaradi pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Mamelodi Sundowns ni orilẹẹde South Africa.

Ọdun 2017 ni Bolt fẹyin ti nibi ere ori papa.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: