Arsene Wenger: Emi ko kundun idabobo isẹ mi

Arsene Wenger

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arsene Wenger sọ wipe didaabo bo ise oun ni nkan ti ko je oun logun lẹyin igba to fidi rẹmi l'ẹmẹfa ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjila.

Ikọ Arsernal yoo gba Manchester City, to nlewaju idije liigi Premier lalejo lọjọbọ, ọjọ kẹrin osu kẹrin lẹyin igba ti Man City fimu wọn fon fere ni asekagba idije Carabao ni papa isere Wembley.

Arsenal wa lẹyin Man City pẹlu ami ayo mẹtadinlọgbọn (27) lori atẹ igbelewọn liigi, wọn si wa lẹyin Tottenham to wa nipo kẹrin pẹlu ami ayo mẹwa.

Arsenal n ba Tottenham dupo kẹrin nitori ati wọ idije Champions League.

Wenger, to jẹ olukọni Arsenal lati ọdun 1996, sọ wipe nkan "iyalẹnu lo jẹ fun oun wipe oun ni lati dahun awọn ibere wọnyii".

Ọmọbibi ilẹ Faranse naa, to jẹ ẹni ọdun mejidinladọọrin tọwọbo iwe adehun wip,e oun yoo ba ẹgbẹ agbabọọlu naa sisẹ fun ọdun meji sii ninu osu karun ọdun 2017.

Eyi waye lẹyingba to lewaju ẹgbe naa to fi gbe ipo keta ninu idije FA Cup, to si kuna lati gbe ẹgbẹ naa wọ idije Champions league fun igba akọkọ laarin ogun ọdun.

O sọ wipe: "Mo kọ lati gba ti gbogbo agbaye nitori ati mu adehun mi sẹ."

Wenger fikun wipe: "Isẹ mi kọ ni nkan to jẹ mi logun ju. Nkan to jẹmi lọkan bayi ni kawọn ikọ mi kọju mọ ifẹsẹwọnsẹ taa ni lola."

Lọjọbọ, Arsenal to wa nipo kefa lori atẹ igbelewọn idije ligi Premier wọn yoo fẹsẹwọnsẹ pẹlu Tottenham. Ti wọn ba bori wọn, wọn yoo wa lẹyin ẹgbẹ agbabọọlu ariwa London naa pẹlu ami ayo meje.