Arsenal vs Man City: Ikọ mejeeji ti gbaradi

Aworan Sergio Aguero

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Igba kan pere ni Manchester City na Arsenal lati bii igba mejilẹlọgbọn ti wọn ti jo figagbaga ninu ifẹsẹwọnsẹ

Ninu idije Premier League, Arsenal yoo ma koju Manchester City lọjọbọ, ni agogo mẹsan ku isẹju marundinlogun.

Arsenal fidi rẹmi lọjọ Aiku ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Manchester City, eleyi ti wọn lu wọn pẹlu ami ayo mẹta sodo.

Ninu ọrọ rẹ, akọnimọọgba fun ikọ Arsenal, Arsene Wenger sọ wipe inu oun bajẹ si alubami ti ikọ Manchester City na awọn lọse to kọja, sugbọn awọn ti ṣe tan lati pada sipo.

Pep Guardiola to je akọnimọọgba fun ikọ Manchester City sọ wipe ko si igba ti awọn koju ikọ Arsenal ti ifigagbaga naa kii gbomi, amọ, awọn ti gbaradi lati tun jawe olubori ninu idije Premier League.