EPL: Manchester city f'agba han Arsenal pẹlu ami ayo mẹta

Leroy Sane, Kyle Walker ati Bernardo Silva Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Manchester city san bantẹ iya fun Arsenal pẹlu ami ayo mẹta

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti fi agba han ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal pẹlu ami ayo mẹta sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ bọọlu Premiership nilẹ Gẹẹsi ni alẹ ọjọbọ ni papa iṣere Emirates.

Eyi jẹ ẹẹkeji laarin ọjọ marun ati ẹẹkẹta ninu saa bọọlu yii ti ikọ Manchester City yoo fiya jẹ Arsenal.

Pẹlu ifẹsẹwọnsẹ yi, Manchester City nilo lati pegede ninu awọn idije marun pere ninu idije mẹwa to ku bayii lati gba ife ẹyẹ Premier League ti saa yi.

Olukọni ere bọọlu fun ikọ Manchester City, Pep Guardiola sọ wi pe awọn ti sunmọ gbigba ife ẹyẹ yii.

"Awọn wọnyi ni awọn aṣekagba igbesẹ ti o kangun si opin idije saa yi, a gbọdọ duro ṣinṣin dopin."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ironu ti ba olukọni ẹgbẹ Arsenal bayii

Lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City lu Arsenal ninu aṣekagba idije ife Carabao pẹlu ami ayo mẹta ni ọjọ aiku, wọn tun f'agba han ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ni ẹyinkule wọn.

Bernardo Silva lo kọkọ yẹ ile wo laarin iṣẹju mẹẹdogun ti idije bẹrẹ, ki David Silva to ju omiran s'awọn ti Leroy Sane si jẹ ikẹta.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bernardo Silva lo kọkọ yẹ ile wo laarin iṣẹju mẹẹdogun ti idije bẹrẹ

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ni anfaani lati gba ami ayo kan wọle pẹlu gbe-silẹ-gbaa-wọle ti wọn ni, ṣugbọn Pierre-Emerick Aubameyang gba bọọlu sọwọ aṣọle Manchester City.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si:

Related Topics