Cedric Bakambu l'agbabọọlu to wọn ju l'Afirika

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Cedric Bakambu ni agbabọọlu Afrika to wọn ju lọ
Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede DRC, Cedric Bakambu, ti di agbabọọlu ti o wọn ju l'Afirika lẹyin igba to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Beijin Guoan, to wa ni China.
Ẹnikan to sunmọ agbabọọlu naa sọ fun akọroyin BBC wipe owo ti wọn ra agbabọọlu naa to aadọruun miliọnu dọla owo orilẹede Amẹrika, iyẹn owo to le ni biliọnu mejilelọgbọn baira.
Owo naa ju miliọnu mẹtadinlaadọrin dọla owo ilẹ Amẹrika, iyẹn biliọnu mẹrinlelogun naira, ti Arsenal ra Pierre-Emerick Aubameyang lati ẹgbẹ agbabọọlu Borussia Dortmund lọ.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakannaa ni owo yii tun ju miliọnu mẹtadinladọrin ti ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool fi ra Naby Keita lati ẹgbẹ agbabọọlu Red Bull Leipzig lọ.
Oríṣun àwòrán, Getty Images