Premier league: Burnley na Everton lati di ipo keje mu sinsin

Awọn ikọ agbabọọlu Burnley n yo lori iṣẹ̀gun wọn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ikọ agbabọọlu Burnley n yo lori iṣẹ̀gun wọn

Ẹgbẹ agbabọọlu Burnley ti na Everton pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan

Ẹgbẹ agbabọọlu Everton lo kọkọ gba ayo wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Atamataṣe ilẹ Turkey, Cenk Tosun, lo kọkọ gba bọọlu wọ inu awọn fun Everton lẹyin ogun isẹju ti wọn bẹrẹẹ ifẹsẹwọnsẹ naa.

Sugbọn Ashley Barnes daa pada fun ikọ Burnley nigbati ifẹsẹwọnsẹ wọ isẹju kẹrindinlọgọta.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ẹgbẹ agbabọọlu mejeji gbiyanju lẹyin igba naa, kosi ẹni to gba bọọlu wọnu awọn ara wọn.

Ọgọrin isẹju ni Chris Wood fi ọba lee fun Burnley.

Kaka ko san fun ikọ agbabọọlu naa ni iṣẹju kẹrindinlọgọrun ni agbabọọlu Everton, Ashley Williams gba kaadi pupa ti oludari ifẹsẹwọnsẹ naa si lee jade lẹyin to se asemase.

Related Topics