Man City vs Chelsea: Conte ni ẹgbẹ Pep le ṣe n t'ẹnikan o ṣe ri

. Image copyright Rex Features
Àkọlé àwòrán Manchester City nilo ami mẹjidinlogun ninu ifẹsẹwọsẹ mẹwa ki wọn o to le ni to ọgọruun ami ayo ninu idije Premier League l'ọdun yii

Olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Antonio Conte, wipe Manchester City le di ẹgbẹ agbabọọlu akọkọ ti yoo ni to ọgọruun ami ayo ninu itan idije Premier League ninu saa kan.

Ẹgbe agbabọọlu to lewaju idije Premier League naa ni ami ayo marundinlọgọrin ninu idije naa, wọn si ni lati bori ni ifẹsẹwọnsẹ maarun ninu mẹwa to ku.

Chelsea, ti yoo ba City lalejo lọjọ Aiku (l'aago 16:00 GMT), lo ni ami ayo to pọ ju ninu itan idije naa (ni saa 2004-05), wọn ni to ami ayo marundinlọgọrun nigba naa.

Conte sọ wipe: "O ṣeṣe ki wọn ni [to ọgọrun ami ayo] nitori wipe wọn fi han wipe awọn ni wọn mọ bọọlu gba julọ ninu idije naa."

Ara orilẹede Italy naa, to gba ife ẹyẹ idije naa pẹlu ami ayo mẹtalelaadọruun ni saa to kọja, s'afikun wipe: "Ti wọn ba tesiwaju pẹlu iru ina yii, pẹlu ebi yii, kosi iye-meji lori wipe won yoo le ri esi yii. (Sugbọn) Koni rọrun."

Ẹgbẹ Man City fi ami ayo mẹdogun siwaju ẹgbẹ agbabọọlu to wa lẹyin wọn ninu idije naa.

Ẹgbẹ naa si le ni to ami ayo marunlelọgọruun to ba bori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹwa to ku fun un.

Gẹgẹ bi Chelsea, ẹgbẹ agbabọọlu naa ni lati koju Manchester United lọjọ keje osu kẹrin ati Tottenham lọjọ kẹrinla osu kẹrin.

Ami ayo ninu idije bọọlu to ga julọ nilẹ Gẹẹsi Ẹgbe agbabọọlu Saa
95 Chelsea 2004-05
93 Chelsea 2016-17
92 Man Utd 1993-94
91 Man Utd & Chelsea 1999-00 & 2005-06
90 Everton, Liverpool, Arsenal & Man Utd 1984-85, 1987-88, 2003-04 & 2008-09

Conte jẹ 'agba akọnimọgba'

Sugbọn olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Man City, Pep Guardiola ti s'apejuwe Conte gẹgẹ bi "agba" akọnimọgba ti yoo fi erepa rẹ silẹ ninu bọọlu ilẹ Gẹẹsi.

Akọnimọgba ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Italy nigba kan rii, Conte, yan tito awọn agbabọọlu rẹ ni 5-3-2 layo, pẹlu bẹẹ losi fi jẹ ife ẹyẹ idije Premier League ni saa rẹ ta akọkọ.

Sugbọn awọn the Blues wa lẹyin City to lewaju idije naa bayi saaju ki wọn to gba ifẹsẹwọnsẹ wọn ni Manchester.

Guardiola sọ wipe: "Mo lero wipe Conte yoo fi nnkankan lẹ fun bọọlu ilẹ Gẹẹsi. Mo ni aridaju nipa bẹẹ."

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ife ẹyẹ Carabao ni ife ẹyẹ akọkọ ti Manchester City gba labẹ akoso Pep Guardiola

Related Topics