Klopp yọnu si Mo Salah lẹyin ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Newcastle

Mo Salah Image copyright PA

Olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp, ni oun fẹran bi Mohamed Salah ti n jẹ bọọlu lẹyin igba ti ikọ rẹ f'agbara kun agbara ninu awọn ẹgbẹ mẹrin to le waju idije Premier League pẹlu fif'agba han Newcastle.

Oku iseju meji ti wọn yoo fi lọ isimi ilaji asiko ni Alex Oxlade-Chamberlain ba taari bọọlu si Salah, ti Mohamed Salah si gba bọọlu kẹrinlelogun rẹ ninu saa yii sinu awọn .

Sugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ko fẹ duro lori ami ayo kan.

Won ja fita-fita lati jẹ si.

Iyanju wọn ko ja si nnkankan titi ti igba ti Sadio Mané fi gba bọọlu ti Roberto Firmino gba si sinu awọn.

Eleyi lo sọ iye bọọlu ti ẹgbẹ gbabọọlu Liverpool jẹ labe Jurgen Klopp di igba.

Salah fẹẹ jẹ bọọlu ẹlẹkẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, sugbọn o subu nipari ere naa. O da bi ẹni wipe agbabọọlu Newcatstle, Jamaal Lascelles, lo ti subu. Klopp sọ wipe ko tọ bi alakoso ere naa ti kọ lati fun Newscatle ni itanran gbe-silẹ-ko-gba-sile ati kadi pupa ti lile jade fun Jamaal Lascelles.

Related Topics