Arsenal fidirẹmi lẹẹkẹta laarin ọjọ mẹjọ

Wenger ati awọn ikọ rẹ dorikodo, wọn fọwọ leran Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Nkan o dagun fun Arsenal bayii ri fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin

Agbabọọlu ọmọorilẹede Naijiria ni, Alex Iwobi ko lee dawọ iya duro fun ikọ agbabọọlu rẹ, iyẹn Arsenal pẹlu bi oun ati awọn akẹgbẹ rẹ tun se bu omi iya mu ninu idije liigi premiership ilẹ Gẹẹsi to waye lọjọ̀ aiku.

Ami ayo meji si ẹyọ kan ni Brighton ti wọn lọ ba nilẹ fi gbẹyẹ mọ wọn lọwọ.

Image copyright ALLSPORT/Getty Images
Àkọlé àwòrán Eyi ni igba kẹta laarin ọjọ mẹjọ ti ikọ agbabọọlu Arsenal fidirẹmi

Eyi ni yoo si jẹ igba kẹta laarin ọjọ mẹjọ ti ikọ agbabọọlu Arsenal fidirẹmi.

Ki isẹju kẹrindinlọgbọn ifẹsẹwọnsẹ naa to ko ni Arsenal ti mu bọọlu ninu awọn wọn lẹẹmeji ọtọọtọ lẹyin ti agbabọọlu Brighton, Lewsi Dunk ati Glenn Murray ti gba bọọlu wọ inu awọn Arsenal ni isẹju keje ati ikẹrindinlọgbọn ifẹsẹwọnsẹ naa.

Image copyright ALLSPORT/Getty Images
Àkọlé àwòrán O daju wipe abajade ifẹsẹwọnsẹ yii yoo tubọ mu ki ẹnu o maa kun olukọni ikọ agbabọọlu naa, Arsene Wenger

Amọsa, Pierre-Emerick Aubameyang da ẹyọkan pada ni igbati o ku isẹju meji ki wọn pari abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ko jẹ iyalẹnu o wipe bi ifẹsẹwọnsẹ naa se bẹrẹ lawọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal kan ti n pariwo, " Wenger yoo lọ!" ni papa isire naa.

Eyi ni yoo jẹ ifẹsẹwọnsẹ kẹjọ ti Arsenal yoo ti maa fidirẹmi ni ọdun 2018 nikan eleyi ti akọsilẹ fihan wipe ko sẹlẹ rii ti Arsenal yoo maa padanu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin tẹlera.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal kan n pe fun idaduro Wenger gẹgẹbii olukọni ikọ naa

O daju wipe abajade ifẹsẹwọnsẹ yii yoo tubọ mu ki ẹnu o maa kun olukọni ikọ agbabọọlu naa, Arsene Wenger ti pupọ awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa n pariwo rẹ wi pe asiko to ko fi ipo silẹ gẹgẹbii olukọni ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.

Pẹlu ifẹsẹwọnsẹ yii, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal yoo si di ipo kẹfa rẹ mu ninu atẹ igbelewọn liigi premiership ni ilẹ Gẹẹsi nigbati Brighton yoo si maa wa ni ipo kejila rẹ.