Enyimba, Akwa United gunlẹ fun idije ife ẹyẹ CAF

Awọn agbabọọlu Enyimba ninu baluu Image copyright @EnyimbaFC
Àkọlé àwòrán Enyimba wa lara awọn odu ẹgbẹ agbabọọlu ni Afirika

Ikọ agbabọọlu Eyimba ti orilẹede Naijiria ti gunlẹ si ilu Cotonou lorilẹede Benin fun abala komẹsẹ o yọ akọkọ ninu idije CAF Confederations cup ti yoo waye ni papa isire Stade de l'Amitié de Kouhounou, Cotonou lọjọọru.

Ẹgbẹ Agbabọọlu Enyimba ti ilu Aba yoo maa koju ikọ agbabọọlu Energie FC ti ilu Cotonou ni ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ipele naa.

Bi ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Enyimba ba ti n waako pẹlu Energie FC naa ni ẹgbẹ agbabọọlu miran lati orilẹede Naijiria, Akwa United FC pẹlu yoo maa koju Al-Ittihad ti orilẹede Libya ni Tunisia.

Image copyright @AkwaUnited_fc
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ agbabọọlu Akwa United gbẹyẹ mọ Hawks ti orilẹede Gambia lati de ipele yii

Ni orilẹede Tunisia ni ẹgbẹ agbabọọlu Al-Ittihad ti n gba awọn ifẹsẹwọnsẹ rẹ nitori wahala eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Libya ni lọwọlọwọ.

Akwa United f'agba han ẹgbẹ agbabọọlu Hawks lati orilẹede Gambia pẹlu ami ayo mẹta si meji lati lee kopa ni ipele yii.

Related Topics