Goolu Messi gbe Barcelona bori Atletico Madrid ni La Liga

Lionel Messi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Messi jẹ iṣoro nla fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti Barcelona ba doju kọ

Lionel Messi gbaami ayo kan wọle ninu idije ifẹsẹwọnsẹ laarin ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ati Atletico Madrid ni papa iṣire Camp Nou.

Pẹlu ifakọyọ yii, ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ti wa ni ori oke tente tabili La Liga ti wọn si n fi ami mẹjọ tayọ awọn akẹgbẹ wọn.

Atletico bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa lẹyin ti wọn ti ṣe aṣeyọri to pegede ninu awọn ere idije diẹ sẹyin.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Lionel Messi jẹ ami ayo kan ṣoṣo ninu idije yii

Gbogbo igbiyanju wọn lo jasi pabo nigbati wọn dojukọ ikọ agbabọọlu Barcelona ni Camp Nou amọsa akitiyan wọn ko mu aṣeyọri kankan wa.

Messi ti o gba ami ayo kan ṣoṣo wọle ninu idije ifẹsẹwọnsẹ yi ni abala akọkọ eyi lo fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ni ami mẹta ti wọn fi jawe olubori ninu idije naa.

Ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona yoo koju agbabọọlu Malaga ti Brown Ideye ngba bọọlu fun ninu ifẹsẹwọnsẹ ti o kan lọsẹ.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si:

Related Topics