Alatilẹyin Arsenal: Afi ki Arsene Wenger lọ

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Arsene Wenger ti gba ami ẹyẹ mẹrindinlogun fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lorilẹede Naijiria ti sọ wipe ọna abayọ si ijakulẹ Arsenal ni saa yii ni kii akọnimọọgba wọn, Arsene Wenger fi ipo rẹ silẹ.

Eyi waye lẹyin ti Arsenal fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City lẹẹmeji laarin ọjọ mẹrin, ati wipe wọn ti fi idi rẹmi nigba meje lọdun 2018.

Lara awọn olulufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Gomina ipinlẹ Ọsun, Rauf Arẹgbẹsọla, so lori itakun twita pe yoo nira lati ri bi oludari Arsenal, Arsene Wenger se maa duro lẹyin esi ifẹsẹwọnsẹ naa.

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọlu Arsenal lorilẹede Naijiria, nigba ti wọn n ba akọrọyin BBC sọrọ ni, ifidirẹmi ọhun mu ibanujẹ ba ọkan awọn.

Olorin takasufe, Sound Sultan ati apanilẹrin nni, Gbenga Adeyinka sọ wipe olukọni ẹgbẹ agbabọọlu naa ni isoro ẹgbẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Arsene Wenger gbọdọ lọ'

Ẹ jẹ ki Wenger pari saa yii

Ninu ọrọ rẹ, Sultan ni ọna abayọ ni kii Wenger o gba ile rẹ lọ, sugbọn Adeyinka sọ wipe nitori Wenger ti se isẹ takuntakun fun ẹgbẹ naa, ki wọn fun-un laaye ko pari saa yii.

Lẹyin naa, o ni ki wọn gba akọnimọgba miran ti yoo ra awọn agbabọọlu to gbajugbaja lati da Arsenal pada sipo, sugbọn ki wọn mase lero wipe ohun gbogbo yoo pada sipo lẹẹkan naa.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Arsene Wenger ti lo ọdun mọkanlelogun gẹgẹ bi akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal

Gomina Arẹgbẹsọla, lori itakun agbaye twitter rẹ, fisita wipe asiko ti to fun Arsene Wenger lati lọ, sugbọn awọn eniyan bu ẹnu atẹ lu ero rẹ, ti wọn si n beere idi ti gomina naa fi wa nipo gomina lẹyin tawọn eniyan fi ẹhonu han lori isejọba nipinlẹ rẹ.

Ti a ko ba gbagbe, Arsene Wenger ti lo ọdun mọkanlelogun gẹgẹ bi akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, to si ti gba ami ẹyẹ mẹrindinlogun fun ẹgbẹ agbabọọlu naa. Ọdun to kọja ni akọnimọọgba naa buwọ lu iwe lati sisẹ fun ọdun meji mii si pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: