Serena n gbero lati ṣe idije tennis f'awọn obinrin ni Afirika

Serena Williams
Àkọlé àwòrán,

Serena Williams ni naa ni yoo dun mọ oun ninu ni lati kopa ninu idije tennis kan lori ilẹ Afirika

Gbajugbaja elere bọọlu tennis ni, Serena Williams ti sọ wipe bopẹ boya, oun yoo ṣe eto idije WTA tennis kan ni ilẹ Afirika.

Serena Williams s'ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC.

Gbajugbaja elere bọọlu tennis ni naa ni ohun ti yoo dun mọ oun ninu ni lati kopa ninu idije tennis kan lori ilẹ Afirika.

O ni paapaa julọ fun awọn obinrin, irufẹ idije bẹẹ yoo dara yoo si kun fun ọpọlọpọ ayọ ati idunnu.

"Nkan ti mo ti n gba lero ni inu mi si dun wi pe, ẹ mu ẹnu baa nitori wi pe funmi, nkan manigbagbe ni yoo jẹ. O daju wipe itaniji ati awọn elere idije bọọlu Tennis ti yoo tipasẹ bẹẹ jade yoo dara pupọ fun idagbasoke ere idaraya naa l'Afirika"

Àkọlé àwòrán,

Serena: orilẹede Kenya lo wa lọkan oun lati ṣe e

Nigba ti wọn bii siwaju sii wipe orilẹede wo ni yoo fẹ lati gbe idije bẹẹ lọ, Serena ni 'orilẹede Kenya lo wa lọkan oun lati ṣe e'.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: