Real Madrid f'agba han PSG ninu Champions league pẹlu ayo meji s'ọkan

Cristiano Ronaldo Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Igba marundinlogun ni Christiano Ronaldo ti gba bọọlu sinu awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹsan to gba sẹyin ni sisẹ̀ n tẹle

Ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ti f''agba han awọn ẹlẹgbẹ wọn, Paris St-Germain nigbati wọn yọ ọwọ wọn ninu awo ni papa iṣire Parc des Princes.

Madrid jẹwọ ai le ja nii jẹ ojude babaa mi o de ihin, fun PSG ninu ipele komẹsẹ o yọ ọ akọkọ ninu idije Champions liigi saa yi pẹlu bi wọn ṣe bori ninu ifẹsẹwọnsẹ mejeeji.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Karim Benzema jẹ ami keje fun Real Madrid

Ni apapọ Real Madrid na PSG pẹlu ami ayo marun si meji.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Cristiano Ronaldo gba ami ayo meji wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ, eyi ti Real bori pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọ kan ti o dẹ tun f'ori gba bọọlu s'awọn lorilẹede France lalẹ ọjọ iṣẹgun.

PSG ni ijakulẹ lẹyin ti adari idije yọ Marco Verratti lẹyin ẹṣẹ meji pẹlu kaadi lọọjokojẹẹ, ṣaaju ki Edinson Cavani too da ami ayo kan pada fun ikọ rẹ.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Aṣiṣe Casemiro fun PSG ni ami ayo, lẹyin to kolu Edinson Cavani

Related Topics