Orilẹede Sierra Leone dibo yan aarẹ tuntun

Obinrin kan n dibo lorilẹede Sierra Leone Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan to lori ila lọwọọwọ lati dibo wọn

Awọn ọmọ ilẹ Sierra Leone to le ni milliọnu mẹta n dibo yan aarẹ tuntun lọwọlọwọ, ati awọn to n lọ sile igbimọ asofin apapọ pẹlu awọn asofin labẹle.

Ni olu ilu orilẹede naa, Freetown, awọn eniyan to lori ila lọwọọwọ lati dibo wọn, t'awọn miran si ti wa nibẹ kii ojumọtomọ.

Aarẹ orilẹede naa, Ernest Bai Koroma yoo fi ipo rẹ silẹ lẹyin to ti ṣe ijọba saa ọlọdun marun fun igba meji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIdibo sipọ aarẹ ati ile igbimọ asofin yoo waye ni Sierra Leone loni

Ẹni ti aarẹ Koroma yan laayo lati fi ipo silẹ fun, Samura Kamara n figagbaga pẹlu awọn oludije marundinlogun miran - eleyii ti ọpọlọpọ wọn seleri lati koju iwa ibajẹ ati oṣi lawujọ orilẹede naa.

Ọgbẹni Kamara to n dije labẹ ẹgbẹ oselu All People Congress jẹ ọkan lara awọn oludije to gbajugbaja.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Awọn yooku si ni Julius Maada Bio lati ẹgbẹ alatako Sierra Leone People's Party (SLPP) nigbati Kandeh Yumkella to jẹ asoju tẹlẹri fun orilẹede naa ninu Ajọ Agbaye, UN n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu tuntun National Grand Coalition (NGC).