Buhari gb'alejo ife ẹyẹ agbaye FIFA nilu Abuja

Aarẹ Buhari gba ife ẹyẹ agbaye soke Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Aarẹ Muhammadu Buhari seleri iranwọ ati atilẹyin to ba yẹ fun ikọ agbabọọlu Super Eagles

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti gba'lejo ife ẹyẹ bọọlu agbaye ni ilu Abuja.

Ni ọjọọru ni awọn alasẹ ere bọọlu lagbaye gbe ife ẹyẹ naa ka aarẹ Buhari mọ ile ijọba Aso rock nilu Abuja gẹgẹbi itaniji ati ipolongo ti o nlọ lọwọ lori idije ife ẹyẹ agbaye fun bọọlu afẹsẹgba ti yoo waye lorilẹede Russia ni osu kẹfa ọdun 2018.

Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede France ni, Chritian Karembeu lo gbe ife ẹyẹ yii le aarẹ Buhari lọwọ

Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede France ni, Chritian Karembeu lo gbe ife ẹyẹ yii le aarẹ Buhari lọwọ lorukọ ajọ to n se amojuto ere bọọlu afẹsẹgba lagbaye, FIFA.

Ọgbẹni Peter Njonjo to jẹ aarẹ ileeṣẹ Coca cola lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika, lo ko ikọ FIFA sodi lọ si ọdọ aarẹ orilẹede Naijiria.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Ikọ agbabọọlu Naijiria se pegede lati kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari seleri nibi ayẹyẹ naa lati se iranwọ ati atilẹyin gbogbo to ba yẹ fun ikọ agbabọọlu orilẹede Naijiria, Super Eagles nibi idije naa.

Lara awọn to ba aarẹ orilẹede Naijiria peju si ibi ayẹyẹ naa ni ikọ agbabọọlu Naijiria to se ipo keji nibi idije ife ẹyẹ bọọlu fun awọn agbabọọlu to n gbabọọlu jẹun nilẹ Afirika pẹlu ikọ akọkọ lati ilẹ Afirika ti yoo kopa nibi idije olimpiiki orii yinyin to pari lorilẹede South Korea laipẹ yii.

Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Ife ẹyẹ agbaye yoo farahan ni ileesẹ BBC to wa ni ilu Eko ni ọjọ ẹti gẹgẹbii ara ilakalẹ ajọ FIFA

Ninu ọrọ tirẹ, minisita fun ere idaraya lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Solomọn Dalung ṣalaye wipe bi ikọ agbabọọlu orilẹede Naijiria se pegede lati kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye fun idije bọọlu afẹsẹgba lo fa a ti ife ẹyẹ naa fi de orilẹede Naijiria.

Olori ikọ FIFA nibi ayẹyẹ naa, Ọgbẹni Peter Njonjo ni awọn ilu mọkanlelaadọrun ni ife ẹyẹ naa yoo de ni orilẹede mọkanlelaadọta.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Ọjọ mẹrin ni ife naa yoo lo lorilẹede Naijiria ni ilu Abuja ati Eko

O ni ọjọ mẹrin ni ife naa yoo lo lorilẹede Naijiria ni ilu Abuja ati Eko.

Ni pataki julọ ife ẹyẹ agbaye yoo farahan ni ileeṣẹ BBC to wa ni ilu Eko ni ọjọ ẹti gẹgẹbii ara ilakalẹ ajọ FIFA.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: