Arsene Wenger: Arsenal ja bi ẹlẹṣẹ nidije Europa pẹlu AC Milan

Aaron Ramsey Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Arsenal ko ba fidirẹmi lelekarun ni telentele nigba akọkọ lati ọdun 1977 ki wọn o to fọkọyọ ni San Siro

Olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Arsene Wenger, ṣ'apejuwe ẹgbẹ agbabọọlu rẹ bi ẹlẹṣẹ to n gbiyanju lati dide lẹyin igba ti wọn gba subu lori bi wọn ṣe sọ aiṣedada wọn di afiẹyin ti eegun fisọ.

Arsenal ko ba fidirẹmi lẹlẹẹkarun ni tẹlentẹle nigba akọkọ lati ọdun 1977 ki wọn o to f'akọyọ ni San Siro.

Henrikh Mkhitaryan ati Aaron Ramsey ni wọn gba bọọlu si'nu awọn ti wọn si jẹ ki ẹgbẹ agbabọọlu Wenger jẹ ẹgbẹ to nireti ati de ipele to sunmọ eyi to kangun si aṣekagba idije Europa.

Wenger sọ wipe: "Aṣeyọri to ṣe pataki ni nitori wipe ọsẹ to kọja buru fun wa pupọ."

Awọn ikọ Gunners fi'dirẹmi ninu idije ligi ilẹ Gẹẹsi ni Brighton lọjọ Aiku, lẹyin igba ti Manchester City na wọn lẹmẹji ọtọtọ pẹlu ami ayo mẹta si odo.

Ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Sweden, Ostersunds FK, na Arsenal pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan, ṣugbọn ẹgbẹ Wenger naa tẹsiwaju si ipele ẹgbẹ mẹrindinlogun ikayin ninu idije Europa.

Eleyi lo jẹ ki wọn o koju Milan.

Eyi ti awọn esi idije miiran ninu Europa liigi:

  • Atlético Madrid 3-0 Lokomotiv Moscow
  • Borussia Dortmund 1-2 FC Red Bull Salzburg
  • CSKA Moscow 0-1 Lyon
  • Lazio 2-2 Dynamo Kiev
  • Marseille 3-1 Athletic Bilbao
  • RB Leipzig 2-1 Zenit St Petersburg
  • Sporting Lisbon 2-0 Viktoria Plzen.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: