UK: £700,000 laa fi kọ yara fawọn ẹlẹwọn to jẹ ọmọ Naijiria

Akọyinsi ọkunrin kan to nwo inu ọ̀gba ẹwọn
Àkọlé àwòrán Adehun wa laarin ilẹ Gẹẹsi ati Naijiria lori ati fi ẹlẹwọn sọwọ si ara wọn

Owo toto ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Pọun (£700,000) nilu Ọba yoo na lati fi kọ abala ẹwọn tuntun kan ni ọgba ẹwọn to tobi julọ ni Naijiria eyiti yoo ko awọn ọmọ Naijiria to nsẹwọn nilẹ Gẹẹsi, to fẹ ko wale si.

Owo naa ni UK yoo na lati fi kọ igun kan ti yoo gba ibusun mejilelaadọfa lẹba ọgba ẹwọn Kirikiri to wa nilu Eko.

Akọwe fọrọ ilẹ okeere nilu Ọba, Boris Johnson, to sisọ loju ọrọ yii tun fikun pe, orilẹede Naijiria lawọn ọmọ ilẹ yii to nse ẹwọn lọwọ nilu Ọba yoo ti wa pari ẹwọn wọn.

Ọdun 2014 si ni Naijiria ati UK ti fọwọsi iwe adehun lori igbesẹ kiko awọn ẹlẹwọn to jẹ ọmọ Naijiria wa sile lati pari ẹwọn wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Eyi tumọ si pe ọmọ orilẹede mejeeji to ba sẹ ni eyikeyi orilẹede naa ni wọn yoo di lapanyaka wa si ilẹ baba rẹ lati se ẹwọn.

Apo asunwọn ẹdawo fun aawọ nilẹ Gẹẹsi ni wọn yoo ti mu owo naa.

Gẹgẹbi akọọlẹ ileesẹ eto idajọ ti wi, okoolelọọdurun awọn ọmọ Naijiria lo nsẹwọn nilẹ Gẹẹsi lọdun 2016 eyi to jẹ ida mẹta apapọ awọn ajeji to wa lọgba ẹwọn nibẹ.

Johnson ni inu apo asuwọn ẹdawo fun aawọ, ifẹsẹmulẹ ati eto aabo eyiti yoo pese idagbasoke fawọn orilẹede ti aawọ ti nwayeni wọn yoo ti mu owo ti wọn yoo fi kọ igun ẹwọn naa .

O fikun pe igbesẹ yii yoo seranwọ nibamu pẹlu afojusun ipese eto aabo ati ifẹsẹmulẹ lẹkun iwọ oorun adulawọ