Ọmọ ọdọ ji owo ọga, o tun p‘ago lori rẹ

Akufọ igo Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ara ohun ija oloro to lee pani lara ni akufọ igo wa.

Ọmọ ọdọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Susan Samson da ata lilọ lu ọga rẹ, to si tun gun-un nigo ni adugbo Ejigbo nilu Eko.

Ọga rẹ ọhun, Mistura tii se olukọ nileẹkọ girama kan, lo wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayi nile iwosan Luth nilu Eko nibi to ti ngba itọju, tawọn dokita si ndu ẹmi rẹ lọwọ.

Bi o tilẹ jẹpe awọn dokita tiraka lati jẹki obinrin naa taji saye pada lẹyin isẹ abẹ oniwakati mẹta ti wọn se fun-un, sibẹ ibudo itọju pajawiri lo wa lai mira.

Ọjọ kẹrin osu keji ọdun 2018 ni Mistura gba Susan gẹgẹ bii ọmọ ọdọ lati maa ba se isẹ ile, amọ a gbọ pe ọjọ Ẹti ati Satide to kọja ni ọmọ ọdọ naa ji owo ọga rẹ laiti lo osu kan ninu ile.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ni kete ti Mistura si ri owo to nwa ninu apo Susan, lo ba tilẹkun inu ile ki ọmọ ọdọ naa maa ba raye salọ.

Kia lo si fi isẹlẹ naa to alatọna to ba wa ọmọ ọdọ leti, ọna lati tete raye na papa bora si lo mu ki ọmọ ọdọ naa da ata lu ọga rẹ loju lasiko to nsun ni yara.

Ori ibusun ni ọmọ ọdọ naa ti la igo mọ ọga rẹ lori

Lẹyin eyi ni Susan, tii se ọmọ ilu Ogoja ni ipinlẹ Rivers ba he igo ọti kan to si nlu mọ ọga rẹ lori titi ti onitọun fi daku rangbọndan.

Ariwo ọga rẹ lo mu kawọn aladugbo fura, ti wọn si mu Susan, ẹniti wọn fa le ọlọpa lọwọ.