Ileeṣẹ BBC gba'lejo ife agbaye FIFA nipinlẹ Eko

Ife agbaye FIFA nileeṣẹ BBC
Àkọlé àwòrán BBC gba'lejo ife agbaye FIFA

Ileeṣẹ BBC ti gba'lejo ife ẹyẹ agbaye FIFA nilu Eko.

Ni ọjọ ẹti ni awọn alasẹ ere bọọlu lagbaye gbe ife ẹyẹ naa lọ si ileeṣẹ BBC ni Ikoyi, nilu Eko gẹgẹbi itaniji ati ipolongo ti o nlọ lọwọ lori idije ife ẹyẹ agbaye fun bọọlu afẹsẹgba ti yoo waye lorilẹede Russia ni osu kẹfa ọdun 2018.

Àkọlé àwòrán Igba kẹfa ree ti orilẹede Naijiria yoo maa kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye

Ọga agba fun eto iroyin ni ileeṣẹ BBC lorilẹede Naijiria, Peter Okwoche fi idunnu rẹ han si awọn alaṣẹ ere bọọlu lagbaye fun ipade yii.

Ọgbẹni Okwoche ṣalaye pe ayẹyẹ ọhun fun awọn ololufẹ eree bọọlu ni anfani lati jẹ ẹbun rẹpẹtẹ ati lati ri ife eye naa.

Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ BBC gba'lejo ife agbaye FIFA nipinlẹ Eko

Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede France ni, Chritian Karembeu pẹlu Ọgbẹni Peter Njonjo to jẹ aarẹ ileeṣẹ Coca cola lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika lo ṣi aṣọ loju eegun ife ẹyẹ yii lọwọ lorukọ ajọ to n ṣe amojuto ere bọọlu afẹsẹgba lagbaye, FIFA.

Ọgbẹni Peter Njonjo to jẹ aarẹ ileeṣẹ Coca cola lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika, lo ko ikọ FIFA sodi lọ si ilu Eko.

Àkọlé àwòrán Ife ẹyẹ agbaye yoo wa fun wiwo ni ọjọ abamẹta nilu Eko

O ni ife naa yoo wa ilu Eko fun gbogbo eniyan lati woo ni ọjọ abamẹta.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: