Ẹgbẹ olukọni ya si meji ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ileifẹ

Awọn akẹkọgboye kan n se ajọyọ Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ olukọni nileewe giga fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, OAU nilu Ile ifẹ ti fọ si meji bayii

Nkan o fararọ bayii laarin ẹgbẹ awọn olukọni nileewe giga fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, OAU nilu Ile ifẹ.

Ẹgbẹ olukọni nileewe giga fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, OAU nilu Ile ifẹ ti fọ si meji bayii.

Laipẹyii ni awọn olukọni labẹ isakoso ẹgbẹ awọn olukọni fasiti lorilẹede Naijiria, ASUU se ifilọlẹ awọn ọmọ igbimọ isakoso rẹ tuntun ninu eyi ti Ọmọwe O. A. Ẹgbẹdokun ti di alaga tuntun.

Ni ọjọ kan naa ni ẹgbẹ miran to ya kuro labẹ ẹgbẹ ASUU ni fasiti naa ti wọn pe orukọ rẹ ni CONUA pẹlu yan awọn adari rẹ.

Wahala ati ede aiyede bẹ silẹ laarin awọn olukọni ileewe fasiti OAU lasiko ti awuyewuye suyọ lori ẹni ti yoo se giwa ileẹkọ naa ni ọdun 2017.

Image copyright oauife.edu.ng
Àkọlé àwòrán Ni ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ CONUA de'lẹ lẹyin ti awọn olukọni fasiti ọhun kan ti ni awọn o faramọ bi nkan se n lọ laarin ẹgbẹ ASUU

Bi igun-igun kan an kan laarin awọn olukọ fasiti naa se faramọ ọkọọkan awọn to n du ipo ọhun nigba naa, lo fa iyapa to way laarin ẹgbẹ olukọni fasiti, ASUU nibẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ hilahilo eleyi ti o fẹrẹ la ti isiwọluni lọ nigba naa,ni ẹgbẹ ba tuka si meji, ASUU gan an gan ati CONUA.

Ni ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ CONUA ni awọn o faramọ bi nkan se n lọ laarin ẹgbẹ naa, ni wọn fi da ẹgbẹ tuntun yii silẹ.

Ninu ọrọ rẹ to sọ fawọn oniroyin, alaga ẹgbẹ ASUU nileẹkọ fasiti Ilọrin, UNILORIN, ọmọwe Usman Raheem ni 'wọn ti sọ ẹgbẹ ASUU di ẹgbẹ awọn alagbara kan.'

Amọsa alamojuto ASUU ni ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria, Ọmọwe Alex Odili se apejuwe awọn olukọni to wa ni ẹgbẹ tuntun naa gẹgẹbii awọn ti ko ni ẹkọ tio rọ mọ ẹka imọ iwe.

Kii se ohun tuntun mọ wipe awọn ẹgbẹ ajafẹtọ osisẹ n fọ kaakiri bayii lorilẹede Naijiria, gẹgẹbi ati se rii ni aarin apapọ ẹgbẹ osisẹ gan an lorilẹede Naijiria, iyẹn NLC pẹlu.