Klopp seleri lati mu Salah ati Mane gba ami ẹyẹ Ballon d’Or

Klopp ati Salah n di mọra wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Klopp ni ko si iyatọ laarin awọn agbabọọlu ilẹ Afirika ati awọn agbabọọlu yooku lagbaye" bi awọn anfani to wa fun awọn yooku ba si silẹ fun awọn naa

Olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ti seleri lati ran awọn agbabọọlu rẹ meji Sadio Mane ati Mohamed Salah lati di agbabọọlu to lee gba ami ẹyẹ agbabọọlu to gbayi julo lagbaye, Ballon d'Or.

Agbabọọlu ilẹ Afirika, George Weah to ti di aarẹ orilẹede Liberia bayii nikan ni agbabọọlu ti osi gba ami ẹyẹ yii lasiko to fi n gba bọọlu jẹun fun Monaco lorilẹede France.

Klopp lasiko to n dahun ibeere lori boya Mane tabi Salah lee gba ami ẹyẹ agbabọọlu to gbayi julo lagbaye, Ballon d'Or, sowipe "Afirika n reti ami ẹyẹ yii, orilẹede Germany pẹlu ti n reti rẹ fun ọpọlọpọ ọdun. Ọna yoowu ti a ba lee gba lati se iranwọn ni a o se."

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Agbabọọlu ilẹ Afirika, George Weah to ti di aarẹ orilẹede Liberia bayii nikan ni agbabọọlu ti osi gba ami ẹyẹ agbabọọlu to gbayi julo lagbaye, Ballon d'Or

Klopp ni oun faramọ bi ajọ ere bọọlu ni Afirika, CAF ye yi akoko idije ife ẹyẹ Afirika pada kuro ni osu kini si osu kẹfa eyi to ni yoo fun awọn agbabọọlu to wa lati ilẹ Afirika lanfani ati lee wọ awọn liigi to lamilaaka lagbaye.

Gẹgẹbii Klopp se sọ, " Ko si iyatọ laarin awọn agbabọọlu ilẹ Afirika ati awọn agbabọọlu yooku lagbaye" bi awọn anfani to wa fun awọn yooku ba si silẹ fun awọn naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Goolu mejilelọgbọn ni Salah ti gba wọle fun Liverpool ni saa yii

Nibayii naa, Mohammed Salah ti gba ami ẹyẹ agbabọọlu to yanranti julọ fun igba keji ni sisẹ-n-tẹle bayii nilẹ Gẹẹsi.

Igba mejilelọgbọn ni Salah ti gba bọọlu wọnu awọn fun gbogbo ifẹsẹwọnsẹ to ti gba fun Liverpool ni saa yii.

Ni ọjọ abamẹta ni ikọ agbabọọlu Liverpool ati Manchester United yoo maa waako lati mọ ẹni ti yoo se ipo keji ninu atẹ igbelewọn liigi Premiership ilẹ Gẹẹsi.