Manchester United ko ri anfani to tọ lara Alexis Sanchez - Jose Mourinho

Alexis Sanchez Manchester United Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Alexis Sanchez jẹ ọgọrin bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal saaju ko to darapọ mọ Manchester United lori adehun ọlọdun mẹ̀rin abọ

Akọnimọgba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United, Jose Mourinho, ti sọ wipe ẹgbẹ na ko ti bẹrẹ si ni ri anfani to tọ lori Alexis Sanchez.

Agbabọọlu orilẹede Chile naa to jẹ ẹni ọdun 29, darapọ mọ Man Utd ninu osu kinni lori adehun ọdun mẹrin abọ lẹyin igba ti wọn ṣe pasiparọ rẹ pẹlu Henrikh Mkhitaryan.

Sugbọn atamatase naa ko gba ju bọọlu kan wọ nu awọn lọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ to gba latigba to ti de Old Trafford.

Mourinho sọ wipe: "O n kọ bi yoo se gba bọọlu pẹlu wa, awa naa si n gbiyanju lati ri anfani to tọ lati ara rẹ."

Wahala to wa nibi jijẹ ki agbabọọlu tun tun ko kọkọ mọ ọwọ ikọ tuntun lo faa ti Mourinho ko fi nifẹsi ọja kara-kata agbabọọlu tosu kinni.