Obasanjọ sabẹwo ibanikẹdun si Benue

Olusegun Obasanjo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Obasanjo ni oun to sẹlẹ ni ipinlẹ Benue bani ninu jẹ lọpọlọpọ

Aarẹ orilẹede yii nigbakan ri, Ogagun Olusegun Obasanjo ti ṣe abẹwo ibanikẹdun lọ si ipinlẹ Benue lẹyin ọpọlọpọ ikọlu to waye ni ipinlẹ ọun.

Obasanjọ ṣe abẹwo naa ni ọjọ Ẹti, ti o si fi ododo se ayẹsi awọn eeyan mẹtalelaadọrin ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ọun nigba to n bọ lati ibi ipade kan ni ipinlẹ Borno.

Nigba ti o n sọrọ, Obasanjọ ni isẹlẹ ipaniyan ni ipinlẹ Benue jẹ oun ti o bani ninu jẹ kọja b'otiyẹ, o ni eyi lo faa ti oun fi rii gẹgẹ bi ojuse lati se abẹwo ibanikẹdun ọun.

Bakan naa, aarẹ ana ọun tẹnu mọ idi pataki ti awọn adari se gbọdọ gbaa gẹgẹ bi ojuse wọn lati se'wadii finifini lori oun to sẹlẹ ni Benue, ki wọn si gba ẹbi pe awọn o se ojuse awọn bo ti tọ ati bo ti yẹ.

"A gbọdọ mọ idi ti ipaniyan yii fi n sẹlẹ, ati idi ti a fi gbọdọ wa ọna lati dẹkun rẹ. A o lee sọrọ orilẹede to ni ominira ati eto aabo to peye, ti a fẹ ki idagbasoke wa, ki awọn oludokoowo wa ba dowopọ, ti a ban la iru oun ti ko mọgbọndani bayii kọja."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Obasanjo ni o yẹ ki Ortom wa ni ibi ipade ti oun lọ ni Borno to ba jẹ pe oun gbogbo n lọ deede

Obasanjo wa ni orilẹede Naijiria ko tii mo odo ti yoo dọrunla si lori eto aabo. O ni ni awọn orilẹede to ti goke agba, iru isẹlẹ bayii, ko le lọ lasan lai si iwadii to gunmọ lori bi o ṣe ṣẹlẹ, o si ni oun ni ireti pe, opin yoo de ba iru awọn isẹlẹ bayii.

Wayi, ọgagun Obasanjọ parọwa si Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom lati ma mikan lori ọrọ naa, sugbọn ki o fọwọwẹwọ pẹlu awọn alẹnulọrọ ni ipinlẹ ọun, lati wa ọna abayọ si ọrọ ipaniyan ni gbogbo igba.