Sergio Ramos fi ori papa silẹ lọ ileegbẹ lasiko ti idije n lọ lọwọ

Sergio Ramos Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Real Madrid tun ti sun soke loni lori tabili La Liga lẹyin ti wọn lu Eibar

Ninu idije to waye lọjọ Abamẹta laarin ikọ agbabọọlu Eibar ati Real Madrid ni Sergio Ramos, agbabọọlu ẹyin fun ikọ Madrid ti fi ori papa silẹ lati lọ se gaa ni ile igbọnsẹ.

A gbọ pe oun to to isẹju marun ni Madrid fi gbabọọlu pẹlu ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu mẹwa ko to di pe Ramos ti ile igbọnsẹ de.

Eleyi sẹlẹ nigba ti idije ọun ku bi ogun isẹju ko to pari, ati pe, ni asiko naa, ọmi alami ayo kọọkan ni ikọ agbabọọlu Madrid ati Eibar n gba lọwọ.

Lẹyin igba ti Ramos ti ibi ti o ti lọ gbọnsẹ de ni Christiano Ronaldo gba goolu ẹlẹẹkeji wọle, eyi to fun Real Madrid ni anfaani lati jawe olubori ninu idije ọun pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan.

Nigba ti o n sọrọ lẹyin idije ọun, oludari ikọ agbabọọlu Madrid, Zinedine Zidane sọ pe, "Ramos rele igbọnsẹ fun isẹju diẹ, ko si si nnkan mii lẹyin eyi."

Related Topics