Peter Cech agbabọọlu Arsenal ṣe ohun t'ẹnikan o ṣe ri

Peter Cech, Asọle ikọ Arsenal Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Anfani si wa fun Peter Cech lati tun kọja aami to fi lelẹ yii

Aṣọle ikọ agbabọọlu Arsenal, Peter Cech lo ti ṣe ohun ti ẹnikan o ṣe ri ninu iwe itan bayi o.

Cech ti di aṣọle akọkọ ninu itan liigi premiership ilẹ Gẹẹsi ti bọọlu ko ni wọ awọn rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ igba.

Cech to ti figbakanri sọ ile fun ikọ Chelsea fi orukọ ara rẹ sinu iwe itan pẹlu ifẹsẹwọnsẹ to waye lọjọ aiku ninu eyi ti Arsenal ti fagba han Watford pẹlu ami ayo mẹta si odo.

  • Cech gba ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ni liigi premiership ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹrin ọdun 2004 ninu ifẹsẹwọnsẹ Chelsea ati Man United.
  • Ni ifẹsẹwọnsẹ Chelsea ati Sunderland lọjọ kini oṣu kọkanla ọdun 2007 ni Cech ti gba ifẹsẹwọnsẹ ọgọrun lai gba goolu wọ awọn rẹ.
  • Ni ifẹsẹwọnsẹ Chelsea ati Bolton lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2011 ni Cech ti gba ifẹsẹwọnsẹ aadọjọ lai gba goolu wọ awọn rẹ.
  • Ni ifẹsẹwọnsẹ Chelsea pẹlu Man United, lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2013 ni Cech gba ifẹsẹwọnsẹ igba lai gba goolu wọ awọn rẹ.

Peter Cech darapọ mọ ikọ agbabọọlu Chelsea ni ọdun 2004 nibiti o ti gba bọọlu fun ọdun mọkanla, mejilelọgọjọ ifẹsẹwọnsẹ to gba pẹlu Chelsea lo jẹ wi pe awọn agbabọọlu alatako rẹ ko ri inu awọn rẹ gba bọọlu si.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdun kẹtala ree fun Cech ni liigi Ilẹ Gẹẹsi

Ni ọdun 2015 ni Peter Cech darapọ mọ ikọ Arsenal nibi ti o ti gba ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogoji bayii laisi alatako to gba bọọlu wọ awọn rẹ.

Awọn aṣọle to di awọn wọn pa julọ ni liigi premiership

1. Petr Cech Cechoslovakia 200 Chelsea, Arsenal
2.
3. David James Ilẹ Gẹẹsi 169 city, Portsmouth Liverpool, Aston Villa, West Ham United, Manchester
4. Mark Schwarzer Australia 151 Middlesbrough, Fulham, Chelsea, Leicester City
5. David Seaman Ilẹ Gẹẹsi 140 Arsenal, Manchester City
6. Nigel Martyn Ilẹ Gẹẹsi 137 Crystal Palace, Leeds United, Everton
7. Pepe Reina Spain 134 Liverpool
8. Edwin van der Sar Holland 132 Fulham, Manchester United
9. Tim Howard Amẹrika 132 Manchester United, Everton
10. Brad Friedel Amẹrika 132 Liverpool, Blackburn Rovers, Aston Villa, Tottenham Hotspur

Peter Cech darapọ mọ ikọ agbabọọlu Chelsea ni ọdun 2004 nibiti o ti gba bọọlu fun ọdun mọkanla, mejilelọgọjọ ifẹsẹwọnsẹ to gba pẹlu Chelsea lo jẹ wi pe awọn agbabọọlu alatako rẹ ko ri inu awọn rẹ gba bọọlu si.

Ni ọdun 2015 ni Peter Cech darapọ mọ ikọ Arsenal nibi ti o ti gba ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogoji bayii laisi alatako to gba bọọlu wọ awọn rẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ifẹsẹwọnsẹ okoolerinwo ati mẹta ni Peter Czeck ti gba bayii ni liigi premiership ilẹ Gẹẹsi

Ifẹsẹwọnsẹ okoolerinwo ati mẹta ni Peter Cech ti gba bayii ni liigi premiership ilẹ Gẹẹsi, ninu eyi to ti gba asọle to pegede julọ fun saa liigi mẹrin ọtọọtọ.

David James, agbabọọlu ilẹẹ Gẹẹsi lo n ṣe ipo keji pẹlu ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọjọ.

Nigba to n sọrọ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ikọ Arsenal pẹlu Watford, Czeck ni 'Lootọ ni inu ohun dun ṣugbọn jijawe olubori ti ikọ naa jawe olubori mu inu ohun dun ju eyi lọ nitori fun igba diẹ bayii, nkan o rọgbọ fun ikọ naa".

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: