Idije laarin PAOK Salonika ati AEK Athens foriṣọnpọn

Awọn oṣiṣẹ alaabo n gbiyanju lati da Savvidis pada Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Savvidis bọ s'ori papa lẹyin ti bọọlu ti Fernando Varela gba sinu awọn di ẹkọ

Niṣe ni ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin ẹgbẹ agbabọọlu PAOK Salonika ati AEK Athens ninu liigi Giriki lọjọ Aiku f'oriṣanpọn latari bi aarẹ PAOK ṣe bọ sori papa pẹlu ibọn lọwọ.

Ivan Savvidis gbiyanju lati gbena woju adari ayo pẹlu ibọn kan to fi ha si itan rẹ lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu rẹ gba bọọlu sinu awọn nigba ti idije naa wọ iṣẹju mọkandinlaadọrun, ṣugbọn ti adari ayo naa kọ lati gba a wọle.

Niṣe lawọn agbabọọlu AEK fi ọrọ ṣe ẹni o riyọ, o dile pẹlu bi wọn ṣe sa asala fun ẹmi wọn nipa fifi ori papa naa silẹ.

Lẹyin wakati meji ni wọn to kede pe opin ti de ba idije naa, ṣugbọn iroyin kan ni, adari ayo naa ti yi ero rẹ pada.

Savvidis sọ fun awọn ọmọ ikọ rẹ lati fi ori papa silẹ lẹyin igbesẹ rẹ ọhun, t'oun funrarẹ si yan lọ si ibi ti adari ayo wa ko to di wipe awọn oṣiṣẹ alaabo fa a pada sẹyin.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Savvidis bọ si ori papa pẹlu ibọn to fi ha si itan rẹ

PAOK lo wa n'ipo kẹta ninu liigi Giriki. Bakanna ni wọn o ba gbera soke si pẹlu ami meji kani wọn jawe olubori.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si:

Related Topics