Kwara United yọ John Obuh nipo gẹgẹ bi akọni

Ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United FC Image copyright @KwaraUnitedFC
Àkọlé àwòrán Kwara United FC wa ni bẹtẹlẹ ninu tabili liigi

Awọn alakoso ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United FC ni ipinlẹ Kwara ti kede yiyọ akọnimọọgba ẹgbẹ naa, John Obuh nipo.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita, awọn alakoso ẹgbẹ naa wipe o di dandan fun wọn lati yọ ọwọ akọnimọọgba naa kuro lawo nitori aiṣe deedee ẹgbẹ agbabọọlu ọhun ati awọn ijakulẹ ti wọn nni ninu awọn idije liigi.

Alukoro fun ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United FC, Abdul Bibire, sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United FC ati John Obuh ṣe adehun ati pin gaari lẹyin ti igbimọ kan ti Ọgbẹni Busari Ishola n sakoso rẹ l'ẹgbẹ agbabọọlu.

Gbólóhùn náà tún ṣàlàyé pé ìpinnu náà di dandan láti mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United eyi awọn ọpọlọpọ alatilẹyin rẹ n wa.

Image copyright JOHN OBUH
Àkọlé àwòrán Kwara United wa ni isalẹ patapata lori tabili liigi NPFL pẹlu ami mọkanla pere ninu idije ifẹsẹwọnsẹ mejila

Awọn iṣakoso Kwara United FC tun fi asiko naa dupẹ lọwọ ọgbẹni Obuh julọ fun iṣẹ takuntakun rẹ gẹgẹ bi akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Kwara United wa ni isalẹ patapata lori tabili liigi NPFL pẹlu ami mọkanla pere ninu idije ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn ti gba ni saa yii.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si:

Related Topics