Jose Mourinho: Ijadewa nidije Champions League o jẹ tuntun

Jose Mourinho Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Mourinho has lost at the last-16 stage of the Champions League in four out of 12 seasons

Olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United, Jose Mourinho, sọ wipe yiyọ ẹgbẹ na kuro ninu idije Champions League nile ninu awọn ikọ mẹrindinlogun ko jẹ nkan tuntun.

Agbabọọlu Sevilla, Wissam Ben Yedder, lo ba ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Spain gba bọọlu sinu awọn lẹmeji ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Sevilla ti jawe olubori ni Old Trafford.

Lati igba ti wọn ti fidirẹmi ni ifẹsẹwọnsẹ idije naa lọdun 2011, ẹẹkan ni United de ipele to kangun si eleyi to kangun si taṣekagba idije naa - ibẹ ni Bayern Munich ti bori Manchester United lọdun 2014.

Olukọni Manchester United to fidirẹmi lẹmẹrin nipele naa ninu idije Champions League sọ wipe: "E mi kọ lero wipe gbigba bọọlu wa ko dara to."

O ṣafikun wipe: "E mi ko kabamọ. Mo sa agbara mi, awọn agbabọọlu naa sa agbara wọn. A gbiyanju, a kuna, bi ere bọọlu ṣe ri yẹn."

Itan United ninu idije Champions League lati ọdun 2008
2007-08: wọn gbe ife ẹyẹ naa (wọn na Chelsea lori ipele gbe-silẹ- ko- gba-sile(penalties)) 2012-13: ipele ikọ mẹrindinlogun ikain (Real Madrid na wọn ni 3-2)
2008-09: wọn sikeji ninu idije naa (Barcelona na wọn pẹlu 2-0) 2013-14: wọn de ipele to kangun si ipele to kangun asekagba (Bayern Munich na wọn ni 4-2 )
2009-10: wọn de ipele to kangun si ipele to kangun asekagba ( Bayern Munich bori wọn) 2014-15: won ko wọ idije naa
2010-11: wọn sikeji ninu idije naa (Barcelona na wọn pẹlu 2-1) 2015-16:ipele atẹ igbelewọn
2011-12: ipele atẹ igbelewọn 2016-17: won ko wọ idije naa
2017-18:wọn de ipele to kangun si ipele to kangun asekagba (Sevilla na wọn ni 2-1)

Mourinho sọ wipe: "Mo joko lori aga yii lẹmeji ninu idije Champions League lẹyin igba ti mo ku Manchester United yọ kuro [nipele ikọ meridinlogun ikain] nile, ni Old Trafford.

"Lori aga yii pẹlu Porto [lọdun 2004] ati Real Madrid [lọdun 2013], wọn jade lasiko mejeji naa.

"Ko kii ṣe nkan tuntun fun ẹgbẹ agbabọọlu naa."

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: