Arsenal na Man City lati gba ife ẹyẹ Continental fun igba karun

Ikọ obinrin agbabọọlu Arsenal n dunnu pẹlu ife ẹyẹ wọn Image copyright ALLSPORT/Getty Images
Àkọlé àwòrán Igba kaarun niyi ti ikọ obinrin agbabọọlu Arsenal yoo gba ife ẹyẹ yii

Ikọ agbabọọlu obinrin Arsenal ti gba ife ẹyẹ Continental Tyres ni ilẹ Gẹẹsi fun igba karun lẹyin ti wọn gbẹyẹ mọ ikọ agbabọọlu obinrin Manchester city lọwọ nibi ifẹsẹwọnsẹ asekagba to waye ni papa isire Adams Park.

Agbabọọlu ikọ obinrin Arsenal, Vivianne Miedema lo gba ayo kan soso to la awọn ikọ agbabọọlu mejeeji laarin wọle.

Saaju asiko yii ni Dominique Janssen ti gba bọọlu lu irin ojuule pẹlu bi Arsenal se n kona mọ ikọ manchester city lara.

Amọsa diẹ lo ku ki Nikita Parris pẹlu Jane Ross o gba ikọ Manchester city silẹ sugbọn ti ko bọ sii.

Image copyright ALLSPORT/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ina ayipada to de ba ikọ Arsenal lati igbati olukọni tuntun Joe Montemurro ti darapọ mọ ikọ naa

Saaju ifẹsẹwọnsẹ yii, ikọ Mancity lo gbegba oroke ti wọn si n di gbogbo ife ẹyẹ bọọlu obinrin nilẹ Gẹẹsi mu ati ife ẹyẹ FA ati Woman super cup pẹlu idije Continental tyres .

Sugbọn ina ayipada, to de ba ikọ Arsenal lati igbati olukọni tuntun Joe Montemurro ti darapọ mọ ikọ naa losu kọkanla ọdun 2017, ko tii ku.

Eyi ni igba keji ti ikọ awọn obinrin Manchester city yoo fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ yoowu lati osu karun ọdun 2017, ifẹsẹwọnsẹ mejilelogun ni wọn ti bori ninu mẹẹdogun ti wọn ti gba saaju asekagba yii.

Related Topics