Iwobi, Musa yoo kopa ni ipele Komẹsẹ o yọ ẹlẹni mẹjọ

agbabọọlu Arsenal subu lu agbabọọlu AC Milan kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nkan o dan fun Arsenal ni liigi sugbn o dabi nipe ode n dun ni idije Europa

Ode dun fawọn agbabọọlu orilẹede Naijiria to kopa ninu idije Europa league pẹlu bi ikọ agbabọọlu ti wọn ti n gba bọọlu jẹun se pegede ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lalẹ Ọjọọbọ.

Alex Iwobi pẹlu ikọ Arsenal ati Ahmed Musa pẹlu ikọ CSKA Moscow pegede lati tẹsiwaju si ipele komẹsẹ-o-yọ ẹlẹni mẹjọ, Quarter finals.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orukọ Alex Iwobi wa ninu iwe sugbọn ko gba bọọlu l'Ọjọọbọ

Nibi ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu AC Milan ni papa isire Emirate ni ilẹ Gẹẹsi, AC Milan lo koko gba asọ lara Arsenal nigba ti agbabọọlu AC milan, Hakan Calhanoglu, gba bọọlu sinu awọn Arsenal.

Amọsa n se lo dabi ẹni wi pe AC Milan fi abara kekere gba nla ni pẹlu bii Welbeck ṣe gba meji pada si inu awọn AC Milan ki Granit Xhaka to fọba lee.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ahmed Musa ni tirẹ gba bọọlu s'awọn fun CSKA Moscow

Bi o tilẹ jẹ wi pe Alex iwobi ko kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa sugbọn ami ayo mẹta si ẹyọ kan yii pẹlu meji si odo ti Arsenal ti kọkọ fi na AC Milan mọle ni ọsẹ to kọja lo sọọ di ami ayo marun si ẹyọkan fun ikọ naa lati tẹ siwaju.

Ahmed Musa ni tirẹ gba bọọlu fun CSKA Moscow bi wọn se na olympique Lyon pẹlu ami ayo mẹta si meji.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ ẹti lawọn ikọ to pegede yoo mọ ẹgbẹ agbabọọlu ti wọn yoo koju

Amọ ori lo ko Musa atawọn akẹgbẹ rẹ yọ nitori ilana gbigba ayo wọle nile onile, iyẹn "away goals rule" ni wọn fi tayọ lẹyin ti apapọ ami ayo wọn ku si mẹtamẹta pẹlu bii Lyon ti se na CSKA mọle lọsẹ to kọja pẹlu ami ayo kan.

Ọrọ wa bẹyin yọ nigbati CSKA na Lyon mọ ile rẹ lalẹ Ọjọọbọ pẹlu ami ayo mẹta si meji.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ Arsenal ti gbọnranu kuro ninu ijakulẹ awọ̀n ifẹsẹwọnsẹ mẹta to se akoba fun wọn ni ọsẹ meji sẹyin

Ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, Ahmed Musa gba kaadi ikilọ alawọ ofeefe bakanaa lo gba ayo wọle si awọn Lyon ni igbati ifẹsẹwọnsẹ naa wọ ọgọta isẹju.