Idije Europa: Iwobi ati Ahmed Musa yoo koju ara wọn

Awọn ikọ Arsenal n dunnu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O di dandan ki agbabọọlu orilẹede Naijiria kopa ni ipele to kangun si asekagba ninu idije Europa

Awọn agbabọọlu orilẹede Naijiria meji, Alex Iwobi ati Ahmed Musa, ni yoo maa gbena woju ara wọn bayii ni ipele komẹsẹ-o-yọ ẹlẹni mẹjọ idije Europa bayii pẹlu bi ikọ agbabọọlu Arsenal ati CSKA Moscow yoo se maa waako ni ipele naa.

Pẹlu eyi, o di dandan ki agbabọọlu orilẹede Naijiria o kopa ni ipele to kangun si asekagba idije naa.

Nibi eto "tani yoo koju tani?" Eleyi ti ajọ UEFA se lọjọ ẹti ni wọn ti kede rẹ.

Arsenal bori ikọ agbabọọlu AC Milan lati de ipele yii nigba ti CSKA moscow koju Olympique Lyon.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ karun osu kẹrin ni wọn yoo gba abala akọkọ idije naa

Ọjọ karun osu kẹrin ni wọn yoo gba abala akọkọ ipele naa ni papa isere Emirate nilu London ki wọn to lọ yanju rẹ ni orilẹede Russia lọjọ kejila osu kẹrin kan naa.

Bakanna lawọn ifẹsẹwọnsẹ miran yoo tun waye ninu ipele yii:

RB Leipzig lati orilẹede Germany yoo koju Marseille lati orilẹede France;

Atletico Madrid lati orilẹede Spain yoo koju Sporting Lisbon lati Portugal;

Lazio lati orilẹede Italy yoo koju Salzburg lati Austria.

Related Topics