Liverpool yoo koju Man City nipele ko-mẹsẹ-o-yọ Champions League

Man City ati Liverpool Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Man City ati Liverpool yoo koju arawọn ninu ipele ko-mọ-ẹsẹ-o-yọ idije Champions League

Ifigagbaga laarin ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi meji ni yoo waye ni ipele komẹsẹ-o-yọ ẹlẹnimẹjọ idije Champions League.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ni yoo koju Liverpool nipele ko-mẹsẹ-o-yọ idije Champions League, quarter-final

Liverpool ni ẹgbẹ agbabọọlu akọkọ to na Man city ninu idije liigi ilẹ Gẹẹsi ni saa yii.

Ireti ọpọ onwoye ni wi pe ifẹsẹwọnsẹ laarin awọn ikọ mejeeji yii yoo le diẹ nitori atimaasebọ awọn ikọ mejeeji.

Liverpool naa Man City pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta sugbọn Man City ti kọkọ f'agba han Liverpool pẹlu ami ayo marun sodo ni ipele akoko saa liigi ilẹ Gẹẹsi yii.

Image copyright Getty Images

Related Topics