Spurs ti tẹsiwaju ninu idije FA Cup lẹyin ti wọn na Swansea

Spurs ti de ipele to kagaun si ipele asekagba ninu idije FA Cup Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Spurs ti de ipele to kagaun si ipele asekagba ninu idije FA Cup

Ẹgbẹ agbabọọlu Spurs ti wọ ipele to kagun si ti asekagba ninu idije FA Cup lẹyin ti wọn f'agba han Swansea.

Tottenham naa Swanse ni pẹlu ami ayo mẹta sodo.

Christian Eriksen lo kọkọ ba Spurs jẹ bọọlu niṣẹjukọkanla ti wọn bẹrẹ ere lẹyin igba ti Erik Lamela gba bọọlu si.

Awọn alejo ti ikọ agbabọọlu Swansea gba naa wọn ko ni awọn ko fikun fun wọn.

Sugbọn igbiyanju wọn ko jamọ nnkankan titi di ipari apakinni ere naa nigba ti Erik Lamela gba bọọlu wọle lẹyin igba to gba bọọlu lati ọdọ Moussa Sissoko.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ agbabọọlu Spurs ti wọ ipele to kagun si ipele asekagba ninu idije FA Cup

Lẹyin igba ti wọn bẹrẹ apa keji ifẹsewọnsẹ naa, ni Christian Eriksen ba Spurs jẹ bọọlu ẹlẹkẹta lori iṣẹju kẹtalelọgọta.

Related Topics