CAF: Naijiria ni asoju ẹgbẹ agbabọọlu mẹrin

Awọn agbabọọlu mẹta n figagbaga Image copyright Nigeria League Management company
Àkọlé àwòrán O ti pẹ diẹ ti orilẹede Naijiria ti gba ife ẹyẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ni ilẹ Afirika kẹyin

Ikọ agbabọọlu mẹrin ni yoo maa gbe asia orilẹede Naijiria ninu idije ife ẹyẹ CAF Confederation Cup bayii.

Awọn ikọ agbabọọlu naa ni MFM, Plateau United, Enyimba ati Akwa United.

Eyi si ni igba akọkọ ninu itan idije naa ti orilẹede Naijiria yoo maa ni ikọ agbabọọlu mẹrin ọtọọtọ ninu idje naa.

Eyi ko sa dede waye bikose pẹlu bi ẹgbẹ agbabọọlu MFM ati Plateau united to n soju orilẹede Naijiria tẹlẹ ninu idije CAF champions league se fidirẹmi lopin ọsẹ.

Image copyright Nigeria League Management company
Àkọlé àwòrán Iroyin ayọ ni fun orilẹede Naijiria latọdọ awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu to kopa ni idije Confederations cup

Ẹgbẹ agbabọọlu MC Algers fi iya jẹ MFM pẹlu ami ayo mẹfa si odo lati ja kuro ni idije Champions league.

Bẹẹ naa ni ami ayo kan ti Plateau United fi gbẹyẹ lọwọ Etuile du Sahel ko to lati pa ami ayo mẹrin si meji ti Etuile fi gbẹyẹ mọ wọn lọwọ ni abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa to waye lorilẹede Tunisia saaju rẹ.

Iroyin ayọ ni lẹkunrẹrẹ fun orilẹede Naijiria latọdọ awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu to kopa ninu idije Confederations cup lati ibẹẹrẹ pẹpẹ, iyẹn Enyimba ati Akwa United.

Enyimba na Energie lati orilẹede Benin pẹlu ayo mẹta si meji eyi to sọ gbogbo ayo ti wọn gba di marun si meji.

Akwa united pẹlu na Al ittihad pẹlu ayo mẹta si meji ni ipele gbe silẹ ko gba sile Penalties lẹyin ti wọn ta ọmi.

Idije Liigi Naijiria

Bakanaa ni idije liigi premiership orilẹede Naijiria waye lopin ọsẹ to kọja.

Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ to waye, ẹgbẹ agbabọọlu Lobi stars, kano Pillars ati Akwa United lo di ipo kinni, ikeji ati ikẹta mu nigbati Kwara United, Go Round, Heartland ati FC Ifeanyi Uba wa ni isalẹ tabili igbelewọn liigi orilẹede naijiria.

Atẹ igbelewọn liigi premiership orilẹ̀ede Naijiria.

Ipo Ikọ Agbabọọlu Iye ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba Iye iyatọ laarin goolu ti wọn gba wọle ati eyi ti wọn gba wọ̀ ile wọ̀n Iye aami wọn
1 Lobi stars 13 4 23
2 Kano Pillars 12 6 20
3 Akwa United 10 10 19
4 Yobe Desert stars 12 0 19
5 Plateau United 10 8 18
6 Abia Warriors 13 2 18
7 Enugu Rangers 12 0 18
8 Katsina United 12 6 17
9 Enyimba 11 1 17
10 Rivers United 12 -3 17
11 Nasarawa 13 0 16
12 MFM FC 11 -1 16
13 Niger Tornadoes 12 -2 16
14 Sunshine stars 13 -3 16
15 El-Kanemi Warriors 13 -3 16
16 Wikki Tourists 13 -5 16
17 FC IfeanyiUbah 13 -2 15
18 Heartland 12 -4 13
19 Go round 11 -5 13
20 Kwara United 12 -9 11

Orisun: League Management Company, LMC